SE IMULO DARA DARA OORE-OFE OLORUN LORI AYE E
Samsoni je Nasiri Olorun ti a da lati se olugbala fun awon Isreali sugbon o kuna, O ja Olorun kule, ko le gba awon eniyan re lowo awon Filistini aninilara won. Samsoni so iran nu gegebi adari Isreali, ko ja ogun kan pari si awon Filistini, sugbon o jagun wewewe. Samsoni se isekuse pelu omobirin Filistini, o ko lati fe ikan lara awon omo ilu ibile re. ife ati ikanu re duro ti omobirin Filistini yi o si ba won ja bi won ba see nipa ife aye re. o buru tan awon adari Filistini mo wipe Samsoni ni ife ninu ajoji obirin won se tan lati de ode lori ailera re yi. Won be awon obirin lati de awon fun Samsoni lati mu ki won si paa. Awon Filistini be iyawo Samsoni (Delila) lowe, ti o si je ara Filistini lati wadi asiri agbara Samsoni. Bibeli wipe ‘O si se, nigba ti o fi oro re ro o ni ojoojumo, ti o si see laisinmi tobee ti suuru fi tan okan re de iku. (Awon Onidajo 16:16)
Lopin gbogbo re Samsoni subu sinu awon won, o si salaye asiri agbara re. Samsoni so fun Delila ‘ni oun si so gbogbo eyi ti o wa ni okan re fun un pe, Abe ko kan ori mi ri, nitori pe Nasiri Olorun ni emi se lati inu iya mi wa, bi a ba fa ori mi, nigba naa ni agbara mi yoo lo kuro lodo mi, emi o si di alailera, emi o si da bi okunrin miran. (Awon Onidajo 16:17)
Logan ti Samsoni so asiri agbara re, awon ota ko fi akoko sofo ki won to fa irun ori re. won mu, won yo oju re mejeji, iyoku itan ni. Samsoni ni opin ohun gbogbo ku si ipajo awon ota re.
EKO
Awon omo Olorun ni lati kiyesara, ki won mase se asilo ore-ofe Olorun ninu aye won. Ojuse Olorun ni lati kun wa pelu ore-ofe, o si je ojuse wa lati setoju ore-ofe re lori wa. Ani lati mo bi a o se lo ore-ofe Olorun ki a si loo fun igbeleke ogo Olorun. Esan wa ninu asilo ore-ofe Olorun ati ebun re. nitori na gbogbo iranse Olorun ni lati sora ki a si te Olorun lorun nipa ipe wa.
ADURA
Olorun olufe mase je ki nse asilo ore-ofe re ninu aye mi, ran mi lowo ki nle fi iberu ati ikiyesara tele ilana re, ki nle se aseyori nile aye ati ninu ise iranse mi. Mo gbadura ki o fi sofo gbogbo ilakaka ota lori ore-ofe re laye mi. Je ki awon ota mi ni ijakule, je ki nsin o daradara, je ki nri ere daradara ni aye yi ati ni orun. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
