OLORUN KO KIN SE IPINYA
Jesu Kristi ro awon Farisi ki won ko asa ati esin won sile, ki won si gba omo Olorun nitooto. Bi awon Farisi tintako Jesu Kristi nipa wiwasuu ihinrere fun awon elese, Mesaya pe oye won si atunse pelu alaye yi ‘Okunrin wo ni ninu yin, ti o ni ogorun-un aguntan, bi o ba so okan nu ninu won, ti ki yoo fi mokan di logorun iyoku sile ni iju, ti ki yoo si tose eyi ti o nu lo, titi yoo fi rii. Nigba ti o si rii tan, o gbee le ejika re, o nyo nigba ti o si dele, o pe awon ore ati aradugbo re jo o nwi fun won pe, e ba mi yo, nitori ti mo ri aguntan mi ti o ti nu. Mo wi fun yin, gege bee ni ayo yoo wa ni orun lori elese kan ti o ronupiwada ju lori olooto mokan di logorun lo, ti ko se aini ironupiwada. (Luku 15:4-7).
EKO
Eniyan le pinya, sugbon Olorun ko le pinya. Eleda feran gbogbo eniyan bakan naa, o la owo re gbalau lati gba ati lati yi won pada, gbogbo elese ti o wa ki won le wo ijoba re. baba wa ti nbe ni orun ma nni inu didun lati ri elese ti o ba ronupiwada kuro ninu ese re. bibeli wipe ‘Ayo nbe niwaju awon angeli Olorun lori elese kan ti o ronupiwada’ (Luku 15:7,10)
ADURA
Oluwa Jesu Kristi jowo se igbala fun awon alaigbagbo. Je ki won mo pe iwo ni omo Olorun ti o ku fun ese won, ati ki won yonda aye won fun o. Je ki won gba o ni Oluwa ati Olugbala won, ki won ba le se rere nile aye ati ni orun. Mo si gbadura ki o pa ise Satani run ninu aye onigbagbo, ki won le mu iduro won titi de opin. Nigba ti opin ba si de, je ki a le ki gbogbo eniyan mimo kaabo si orun pelu yiyo niwaju re titi lae. Amin.
