AYO N BE NI ORUN LORI ELESE TO RONUPIWADA
Jesu Kristi wasu lori idariji ese, o si salaye pelu itan omo onina kunan lati gbe iwasuu re lehin. Omo oninan kunan jogun baba re nigba ti baba si wa laye. O ro baba re titi baba re fun ni ogun tire. ‘O si se omode kunrin kan ko gbogbo oro re lo si ile okeere ni bi ti o ti na ni ina kinan laipe ojo. Sugbon o kiyesi re, o si pinu lati pada sile. O be baba re fun idariji, baba re si dariji. Baba so wipe ‘ E mu aayo aso wa Kankan, ki e si fi woo, e si fi oruka boo lowo, ati bata si ese re. E si mu egboro maaluu abopa wa, ki e si paa, ki a ma je, ki a si ma se ariya. Nitori omo mi yii ti ku, o si tun ye, o ti nu a si rii, won si bere si se ariya
(Luku 15:22-24).
EKO
Olorun yi o fi tayo tayo dariji elese ti o ba ronupiwada ese re, ti o si yipada si Olorun. Olorun ati awon Angeli re yi o wo bata ijo, won o si yayo lori eni be e. Jesu wipe bee ni ayo yoo wan i orun lori elese kan ti o ronupiwada ju lori olooto makan din logoorun lo, ti ko se aini ironupiwada (Luku 15:7)
ADURA
Olorun olufe mo mo wipe o feran elese sugbon o korira ese won nitori na, mo pinu lati ko ese mi, ki nsi wa sodo re. emi o fi aye ati agbara mi sin o. mo ma lepa, pelu gbogbo ipa lati gboran si gbogbo ase re, maa si te o lorun. Jowo ko oruko mi sinu iwe iye, ki o si ka mi ye lati le je alabapin ni ijoba re. ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
