MAA TELE ILANA OLORUN NIGBA GBOGBO
Eya Benjamini sote si eya Mokanla Isreali ti o ku, eyi si fa ogun abele. Awon eya mokanla to ku ni isokan, beere itoni lowo Olorun, o si dari won. Sugbon awon eya mokanla Isreali ti won wa ni isokan ko segun nitori won ko tele itoni Olorun. Won ko rewesi, won tun bere itoni lodo Olorun. Ni igba keta pelu titele ase ati ilana Olorun awon isokan eya mokanla Isreali segun eya Benjamini. Bibeli fi ye wa bi Isreali se bori olote eya Benjamini. ‘Sugbon nigba ti awosanmo bere si ru soke lati ilu naa wa pelu gogo eefin, awon ara Benjamini wo eyin won, si kiyesi eefin gbogbo ilu naa goke lo si orun. Awon okunrin Isreali si yipada, awon okunrin Benjamini si daamu, nitori ti won rii pe ibi de ba won. Nitori naa won pehinda niwaju awon okunrin Isreali si ona iju, sugbon ogun naa lepa won kikan ati awon ti o ti ilu wonni jade wa ni won pa laarin won. Bee ni won rogba yi Benjamini ka, won lepa won, won te won mole ni ibi isinmi, ni okankan Gibea si iha-ila oorun. Egbaa mesan-an okunrin ni o subu ninu awon eniyan Benjamini gbogbo awon wonyi ni akoni okunrin. Won si yipada, won salo si iha iju sori okuta Rimmoni won si sa egbeedogbon okunrin ninu won ni opopo, won lepa won kikan de Gidomu, won si pa egbaa okunrin ninu won. Bee ni gbogbo awon ti o subu ni ijo naa ninu awon ara Benjamini je egbaa mejila okunrin o le egberun ti o nko ida, gbogbo awon wonyi ni akoni okunrin. (Awon Onidajo 20:40-46).
EKO
Olorun si ndari awon eniyan loni, o ndari awon omo re ni igbese ti yoo se won ni anfani. Sugbon nkan le ma ri bo ti ye ti a ko ba tele itoni re. A ko ni lati ni iporuru okan nigba ti nkan ko ba lo bi a ti nfe, a ni lati se giri ki a mu aya le ki asi tele ase ati itoni Olorun. A ko ni lati rewesi lati ma to Olorun lo fun itoni nigba gbogbo titi a o fi ri idahun si ebe wa. Baba wa ti nbe lorun yi o gbo igbe ebe wa, yi o si dari wa si isegun.
ADURA
Olorun olufe ko mi kin le tele itoni re, kinba le ni isegun lori ogun aye gbogbo. Ti o ba ndari, je ki nle tele o, bi mo ba ntele o je kin sase yege. Je kin ni isegun ni oni, ni ola, ati ni gbogbo ojo aye mi. ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
