OLORUN LE, YIO SI PA AWORAN ARA RE MO
Awon omo Isreali rope Olorun yi o foju fo ese won, yi o si da bo bo won lowo ota won, sugbon oju ti won. Bi won tile fe fi abetele fa oju Olorun nipa abo iwa mimo, won gba ijiya to to (Isreali gbe Apoti majemu Olorun wa si oju ija, ni ireti pe Eleda yi o jewo wiwa laarin won) Olorun ko lati gbeja fun awon alaigboran omo, eyi si mu ki won padanu apoti eri majemu. O fi ajakale arun ba won ja, o si fi oosa won se yeye ni gbangba. Bibeli wipe ‘Nigba ti awon Filistini gbe apoti Olorun, won si gbe wa si ile Dagoni, won gbee ka ile ni eba Dagoni. Nigba ti awon ara Asdodu ji ni owuro ojo keji ki ye sii, Dagoni ti subu dojubole niwaju apoti Oluwa. Won si gbe Dagoni, won si tun fii si ipo re nigba ti won ji ni owuro ojo keji, kiyesii Dagoni ti subu dojubole niwaju apoti Oluwa, ati ori Dagoni ati atele owo re mejeeji ke kuro ni oju ona, Dagoni sa ni o ku fun ara re. nitori naa awon alufaa Dagoni ati gbogbgo awon tii maa wa si ile Dagoni ko si te oju ona Dagoni ni Asdodu titi di on (Samueli kini 5:2-5).
Bakan naa Olorun pa won run, awon ota ti o fowo kan ogo re, opolopo won ni won ku iku aitojo.
EKO
Olorun kii se eniyan lasan, o je Olorun ti o ga ju lo, a ko ni lati fi we orisa korisa. Olorun yi o sa ipa re lati fi abo bo awon eniyan re. eleda ni agbara lati daloro ki o si pa enikeni ti o ba ba ogo re je. Nitori na gbogbo eniyan ni lati wariri ki won si bu ola fun. Enikeni ki o mase se ohunkohun ti yi o fa ibinu Olorun. Kristieni ni lati lakaka iwasuu ihinrere ki awon alaigbagbo le ni irepo to dara pelu Olorun.
ADURA
Olorun olufe mo ti mo pe o lewu lati se ohunkohun ti yi o fa ibinu re, mo si setan lati wa labe aanu re, lati akoko yi lo mo kanu fun awon ese mi atehinwa mo bebe fun idariji. Emi o fi gbogbo okan mi sin o, mo gbagbo ninu omo re Jesu Kristi, mo si gbaa gege bi Oluwa ati olugbala mi. jowo ko oruko mi sinu iwe iye, ki o si dara fun iyoku igba aye mi, ni oruko Jesu Kristi ni mo gbadura. Amin.
