NI IRELE
Jesu Kristi salaye itumo iwa-erele, O si wipe awon okunrin meji goke lo si tempili lati gbadura, okan je Farisi enikeji si je agbowode eyi Farisi dide, o si ngbadura ninu ara re bayii pe ‘Olorun mo dupe lowo re, nitori ti emi ko ri bi ara iyoku, awon alonilowogba, alaisooto, pansaga tabi emi ko tile ri bi agbowode yii. Emi ngbawe ni eemeji ni ose, mo nsan idamewa ohun gbogbo ti mo ni. Sugbon agbowode duro ni okeere, ko tile je gbe oju re soke orun, sugbon o lu ara re ni ookan aya, o wipe ‘Olorun saanu fun mi emi elese. Mo wi fun yin, okunrin yii sokale lo si ile re ni idalare ju enikeji lo nitori enikeni ti o ba gbe ara re ga, oun ni a o re sile, eni ti o ba si re ara sile, oun ni a o gbe ga. (Luku 18:10-14) .
EKO
Iwa-irele kii se nipa oro enu nikan sugbon nipa ihuwasi wa. Gbogbo Kristieni ni a be ki a ni iwa-irele ki a le te Olorun lorun, anilati fe elomiran bi ara wa ki a si bowo fun won. Ki a mase gbejo enikeni dare sugbon ki a fiwon sipo to to ki a mo wipe eni owo eda Olorun ni won je. Bakan naa Kristieni ni lati gbe ebe adura won to Olorun lo pelu irele. A ko ni lati gbadura pelu igberaga sugbon ki a bere pelu irele niwaju re, ki o ba le da wa lohun ebe adura wa.
ADURA
Olorun olufe se mi ni onirele eniyan, je kin bu ola fun o ni gbogbo akitiyan ati ki emi bowo fun awon elomiran. Jeki emi ma pon eniyan le, kin Pataki won. Si ko mi bi mo se le wasu ihinrere ki awon eniyan le gbagbo ninu Jesu Kristi ki won si di eni igbala. Amin.
