IPADABO JESU
Jesu Kristi fi pipada bo re leekeji fi we igba aye Noa. O dabi ohun gbogbo nlo bo ti ye, nitorina awon eniyan muu ni yepere, ikilo Olorun fun ironupiwada ati igboran. O seni laanu, Olorun pa gbogbo eniyan run yato si ebi Noa, ikun omi gba aye, gbogbo eniyan di oku. Jesu wipe, bi o si ti ri ni ojo Noa, bee ni yi o ri ni ojo omo-eniyan. Won nje, won nmu, won ngbeyawo, won si nfa iyawo fun ni, titi o fi di ojo ti Noa wo inu oko lo, kikun omi si de, o si run gbogbo won. Geege bi o si ti ri ni ojo Loti, won nje, won nmu, won nra, won nta, won ngbin, won nkole sugbon ni ojo naa ti Loti jade kuro ni Sodomu, ojo ina ati sulfuru ro lati orun wa, o si run gbogbo won. Gege bee yoo ri ni ojo naa ti omo-eniyan yoo farahan. (Luku 17:26-30).
EKO
Jesu Kristi yi o pada wa sile aye nigba ti a ko reti, yi o gba awon ayanfe soke orun, yi o si gba awon alaigbagbo sinu ina orun apadii. Awon ti o ba ku yi o wa lowo idaloro Satani (Eda to buru ju) Satani ti a npe ni Esu, yi o fiya je elese ni orun apadi. Lakoko kan naa awon ayanfe ti a ti gba soke yi o wa pelu Jesu Kristi ni orun ninu Alafia ati igbadun ayeraye. Nitori naa anro gbogbo eniyan lati jewo igbagbo won ninu Jesu Kristi, ki won le ye fun igba soke. Jesu Kristi nikan lo je bi agbejoro fun elese ni ojo idajo Olorun. Kristi ti o ku fun awon elese yi sipe fun awon to ba gbagbo ninu re, yi o si yo won kuro ninu idalebi ijiya orun apadii. Olugbala yio kede idalare awon eni mimo re. bakan naa ko ni je ki awon elese wo orun rere.
ADURA
Oluwa Jesu Kristi mo fe lo si orun rere, nko fe lo si orun ina apadii. Mo yonda aye mi fun o loni, mo jewo re ni Oluwa mo si gba o bi Oluwa ati olugbala mi. mo jewo pe lati oni lo, un o sin o nitooto, un o si tele o fun iyoku ojo aye mi. nitori ti moti gbadura, mo jewo ara mi bi omo Olorun a ko oruko mi sinu iwe iye, orun rere si ni ibugbe ikeyin mi. E yin Olorun logo.
