O GBODO MU EJE RE SE
Hana yagan, O gbadura o beere omo kunrin lowo Olorun, o si seleri lati yonda omo re akobi fun ilo Olorun. Hana wipe ‘Oluwa awon omo ogun, bi iwo nitooto ba bojuwo iponju iransebirin re, ti o si ranti mi, ti iwo kosi gbagbe iransebirin re, sugbon bi iwo ba fi omokunrin kan fun iransebirin re nigba naa ni emi o fi fun Oluwa ni gbogbo ojo aye re, abe ki yoo si kan lori. (Samueli kini 1:11)
Olorun gbo adura Hana, o si bi omokunrin kan ti o pe oruko re ni Samueli. Omobirin yi bu ola fun ileri re, o si mu Samueli to Olorun wa. O to wolii Olorun wa, o si wipe ‘Dariji mi, Oluwa mi, bi o se wa laye, emi ni arabirin ti o duro nihin, ti mo gbadura si Oluwa, mo beere fun omo yi, Oluwa si gbo ebe mi. bayii mo fi fun Oluwa, ni gbogbo aye re ni mo fi fun Oluwa. (Samueli kini 1:26-28)
EKO
Enikeni ti o ba se ileri pelu Olorun wa labe eje, iru eni bee nilati mu ileri tabi eje re se. jehofa ko gba ileri kileri si yeye, yi o duro fun amuse gbogbo ileri. Ko si omo Olorun ti yi o je ki ara tuu, ti yi o fi gbagbe ati san eje re fun Oluwa. Opolopo eniyan a maa se ileri tabi eje ni igba isoro. Won a wipe ‘Ti o ba le ran mi lowo ninu akoko yi, emi yi o se eyi ati eyi fun o. lehin ti Olorun ba dahun adura won, won ma ngbagbe eje ti won ba Olorun da. Inu Olorun ko le dun niru akoko yi. O fe ki awon omo re bu ola fun ileri won ki won si fi imore han. O le dawo ibukun ti ojo iwaju duro, titi ti awon omo re yi o fi bu ola fun. Nitori na gbogbo eniyan nilati bowo fun Oluwa, ki won si mu ileri won se.
ADURA
Olorun olufe ma binu bi mo ba ti ko lati mu ileri mi se, mo ronupiwada loni mo si setan lati se atunse ibasepo pelu re. Mo ra pada gbogbo eje mi, un o si mu inu re dun pelu ore mi, emi yi o mu ebo ope nla wa fun o, emi yi o si jeri didara re ninu aye mi fun gbogbo eniyan. Jowo fun mi ni ore-ofe lati le mu ileri mi se, kinsi je ayanfe omo re. ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
