JESU KO NI EGBE
Wolii Jona se aigboran si ase Olorun, o si gbiyanju lati sa pamo niwaju re, sugbon isiro re jaa kule. Jona ti o rin irin ajo lori omi, lo ba ara re pade ninu Eja, o si ri gbigbona ina orun apadi. Olokan lile Jona ronupiwada ninu Eja, o si bebe fun idariji ese re. Olorun dari jii, o si mu bo sipo, Bibeli wipe nigba naa ni Jona gbadura si Oluwa Olorun re, lati inu eja naa wa. O si wipe, Emi kigbe nitori iponju mi, mo kigbe lati inu ipo-oku, iwo si ti gbohun mi. Nitori ti iwo ti so mi sinu ibu, laarin okun, isan omi si yi mi kaariri, gbogbo bibe omi ati riru omi re koja lori mi. (Jona 2:1-3).
EKO
O dara ki a gboran si Olorun ki a si gba ibukun re ju ki a se aigboran ki a si je iya to buru jai. Orisirisi ona ni Olorun ni, lati mu ki a se atunse, o le fi owo irin mu awon omo re titi won yi o fowo owo po pelu re. Enikeni ti o ba gboran ni a nfe lati je ipese Olorun ju eni ti a baa n na ni egba ki o to gboran. Olorun nse odiwon awon omore nipa igboransi won. Yio wa pelu awon ayanfe Omo re to gboran titi laelae, yio dabobo won, yio gba won kuro ninu isoro, yi o si pese fun gbogbo ohun ti won ba nfe.
ADURA
Olorun Olufe, jowo se mi ni omo ti o ngboran. Je kin fetisile gbo, ki nsi se ohun ti o ba so. Fun mi ni okun lati se ohunkohun ti o fe ki emi se. Mase je ki emi fa ibinu re nipase aigboran. Je ko ye mi nigba gbogbo pe iwo ri ohun gbogbo, iwo yio si se idajo ohun gbogbo, yala ibukun tabi ijeniya. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
