Jesu Nikan Ni Ona fun Igbala
Abrahamu, Isaaki, Dafidi ati Jesu Kristi je apere oniwa to dara ninu bibeli, sugbon Jesu Kristi, tayo awon to ku. Gbogbo awon eniyan inu bibeli ku, ara won si dibaje sugbon ki nse bi Jesu Kristi. O ku, o si jinde, ni ojo keta pelu aidibaje ara, Bibeli wipe, ‘Nitori leyin igba ti Dafidi sin iran re tan bi ife Olorun, o sun, a si tee ti awon baba re, o si ri idibaje. Sugbon eni ti Olorun ji dide ko ri idibaje. Nje ki o ye yin, ara, pe nipase okunrin yii ni a nwaasu idariji ese fun yin. Ati nipa re ni a nda olukuluku eni ti o gbagbo lare kuro ninu ohun gbogbo, ti a ko le da yin lare ninu ofin Mose. (Ise Awon Aposteli 13:36-39)
EKO
Jesu Kristi ni omo Olorun ti a ran lati gba araye la kuro ninu ese won. O ku fun ese wa, o si jinde lati fun wa ni iye ainipekun. Gbogbo eniyan ni lati mo pe Jesu Kristijinde lehin ti a pa ti o si ku. Awon elesin wonyi Ku lai si ajinde, Mohamodu ati Budaha ko ji dide lehin iku won. Awon akoni inu bibeli ko ji dide, lehin ti won ku. Bakannaa, awon oniwaasu ati asaju nla igbaani ku lai ji dide. Jesu Kristi nikan lo ji dide kuro nipo oku. Bibeli wipe, enikeni ti o ba gbagbo ninu Jesu Kristi, gege bi omo Olorun, ti o si jewo re ni Oluwa ati Olugbala re ni a o gbala (Romu 10:9-11).
Iru eni bee le ku, ki o si ri idibaje ara, sugbon yi o ji dide ni ojo ikehin, lati je igbadun iye aiyeraye pelu Olorun ni orun. Niwon bi ko see se fun iku lati di Jesu Kristi mu si ipo oku, enikeni to ba gbaa gbo, yi o ji dide ni ojo ikehin, lati gba ebun iye ayeraye. Onigbagbo ninu Kristi yi o gba ade ogo ti kii dibaje lowo Olorun ni orun, won yi o si ni ayo ati ifokanbale pelu Olorun titi laelae.
ADURA
Jesu Kristi Olufe, mo mo wipe o jiya, o si ku lati gba mi la, o si fun mi ni ebu iye ayeraye. Iru ore iyanu, onife ni iwo ise. Mo feran re gidigidi. Mo ti sepinu lati maa sin o ni otito lati oni lo. Mo jewo wipe omo Olorun ni o. Iwo ni Oluwa mi, Olugbala mi, Oba mi. Ni otito emi yi o tele o, emi yi o sin o fun gbogbo aye mi. Mo fi ife okan mi yin o, mo si wipe o seun pe o gba okan mi la. Amin.
