E JE KI A KO EKO LARA AWON IJO AKOKO
Awon ijo akoko ni ede aiyede nipa ikola sugbon Olorun ran won lowo lati yanju re laisi inilara. Opolopo ni o ni iporuru okan nipa ikola aya, won nfe alaye. Nitorina won ran Paulu ati Barnaba lati gbo alaye lati enu awon agba ti won wa ni Jerusalemu. Awon alagba ijo ti o wa ninu Jerusalemu gbadura, won si jiroro, won si ni idahun ti o se koko. Won so wipe Kristeni ti kii se eya Juu, ki won mase fi ipa mu won tele asa Juu. A fi ye wape, ojuse Kristeni ni ki a mase daapo mo asa ibile (Adapo). Awon alagba pase fun awon ijo kekeke ki won wa ni ominira, sugbon ki won mase gbonjege iwa mimo ti Olorun. Bibeli wipe, Ati awon aposteli ati awon agbaagba pejo lati gbimo oran yii. Nigba ti ijiyan si di pupo Peteru dide, o si wi fun won pe, Ara, eyin mo pe, lati ibere Olorun ti yan ninu yin, ki awon keferi ki o le gbo oro ihinrere ni enu mi, ki won si gbagbo. Ati Olorun tii nse Olumoran-okan, o je won ni eri, o nfun won ni Emi Mimo gege bi awa. Ko si fi iyato si aarin awa ati awon, onfi igbagbo we won ni okan mo. Nje nitori naa, eese ti eyin o fi dan Olorun wo, lati fi ajaga bo awon omo-ehin ni orun, eyi ti awon baba wa ati awa ko le ru. Sugbon awa gbagbo pe nipa oore-ofe Oluwa Jesu, awa o la, gege bi awon. (Awon Aposteli 15:6-11)
EKO
Awon ijo oni ye ki won yanju aawo laarin ara won bi ijo akoko se yanju tiwon. Awon ijo akoko gbadura won si jiroro bi won yio se yanju ija ti o wa laarin won. Won gba lati gba imoran lati odo awon alagba won ati nipase idari Emi Mimo. Idi abajo aseyori won niyi. Awon ijo iwoyi yio ni aseyori bi won ba le gba Emi Mimo laye. Ki awon ijo wa yowo ninu oselu, ki awon alagba wa mase maa dibo lori awon ohun ti emi. Oselu yato si Kristeni, ilepa won si yato. Emi ni Olorun, o si ye ki Kristeni wa ninu emi. A nilati gbadura, ki a si feti si idari Emi Mimo, ki a baa le se ipinu ti yi o te Olorun lorun. Ti ijo Olorun ba kun fun adura, jije olooto, Satani yi o padanu ni gbogbo ona re si awon ijo wa, awa o si ni aseyori nla.
ADURA
Olorun Olufe, jowo ji ijo dide ninu orun asupara. Ijo ti tutu awon arakunrin ti soo nu, wiwa oju re fun idahun-abayo fun isoro won. Jowo so awon ijore ji. Je ki a le maa wa oju re fun ohun gbogbo. Je ki awon arakunrin muu ni Pataki adura ati igbe aye iwa mimo ju ohunkohun lo. Je ki a ni ifowosowopo pelu re, ki a le ri ise ami ati ise iyanu bi ti awon ijo akoko. E di awon alagba wa mu, ki o si gba won ninu emi ara ati imotara eni nikan. Je ki awon alagba ijo ati awon omo ijo ni aseyori ni aye, ki a si ye fun igbasoke. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
