AANU N’SOGO LORI IDAJO
Paulu ati Barnaba pinya ilepa won, nigba ti won bere si woye nkan ni ona ti o yato. Sugbon awon mejeji je agbalagba lati le di ijewo igbagbo won mu, lai ja Olorun kule. Bibeli ni akosile akoko iyapa Paulu ati Barnaba wipe ‘Ija na a sipo to bee, ti won ya ara won si meji, nigbati Barnaba si mu Marku, o ba ti oko lo si Kipru. Sugbon Paulu yan Sila, o si lo, bi ati fi Siria ati Kilikia, o n mu ijo ni okan le (Awon Aposteli 15:39-41)
EKO
Arakunrin Kristeni ti won wa ni orisiri ijo, le ma fara mo gbogbo isesi ara won, sibe a si le sin Olorun ni isokan. Won pe wa lati sin Olorun pelu isokan, o ye ki a se eyi lai dojuko iyato asa esin wa. Awujo Kristeni ko ye ki a je ki iyato imoran wa ki o se ipalara fun ihinrere ti Jesu ku fun. Oye ki a keko lara Paulu ati Barnaba, ti won je alaba sise po ninu ogba ajara Olorun, bi o tile je wipe won ni itumo ti o yato lori awon oro-ise kan. Awon mejeeji pinya, lai je ki o se ipalara ihinrere. Paulu ati Barnaba ko faye gba ede aiyede won lati se ipalara fun idapo won pelu Olorun. Won yonju aigboraye won pelu ogbon agba, won si dabobo ise iranse won. Oye ki a menu baa, wipe lehin ipinya awon Paulu ati Barnaba ise iranse won ntesiwaju sii.
ADURA
Olorun Olufe, jowo gba ebi Kristeni ninu etanu ati igbogun iyapa ti o nse idiwo fun ojuse wa. Je ki a maa fi owo bara wa se. Je ki a wa ile ti o teju lati kede ihinrere re. Ran wa lowo, lati paati gbogbo aisokan wa, ki a bowo fun eko inu Bibeli. Je ki Emi Mimo fun wa ni ojulowo itumo awon oro re; ki a si fi won sinu ise ninu aye wa. Ran ijo re lowo lati wa ni ikiyesara, ki a jumo se ipolongo ihinrere ita gbangba, ki a duro ninu ododo re, ki a si dari awon eniyan lati gba igbala re. se wa ni asoju re nitoto ni aye, ki a le gba ere ainipekun ni orun. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
