ITAYO IBI JESU
Itan igbe aye Jesu Kristi peye, o si se pataki. Wundia kan bi Omo iyanu ti o je Olugbala gbogbo aye. Bibeli wipe bi ibi Jesu Kristi tiri niyi, ni akoko ti a fe Maria iya re fun Josefu; ki won to pade, a rii, o loyun lati owo Emi mimo wa. Josefu oko re, tii se olooto eniyan, kosi fe doju ti i ni gbangba, o fe iko o sile ni ikoko. Sugbon nigbati o nro nkan wonyi, woo, angeli Oluwa yosii ni oju ola, o wipe Josefu iwo omo Dafidi, ma foya lati mu Maria aya re si odo nitori ti oyun ninu re lati owo Emi Mimoni.
Yoosi bi omo kunrin kan, Jesu ni iwo o ope oruko re, nitori oun ni yoo gba awon eniyan re la kuro ninu ese won.
EKO
Itan ibi Jesu Kristi ya to patapata si gbogbo eda alaaye. Iya re Maria koloyun re nipa iba lopo pelu okunrin Kankan. O loyun Jesu Kristi nipa ibewo Emi Mimo. Omo iyanu naa dagba ninu ore-ofe, okun ati agbara lati mu ipin aye re se, eyiti o je lati gba araye la. Kristi duro niipo re. O fi okun nla han nipa sise ise ami ati iyanu, o si polongo ijoba Olorun. Mesaya sile kun ona igbala fun gbogbo eniyan lati le di eni igbala. Oku fun elese, o si jindeki o le fun awon ti o gbaagbo ni ebun iye ayeraye. Enikeni ti o ba jewo Jesu Kristi, ni Oluwa ati olugbala re yi o di eni igbala. Igbala Jesu Kristi kii se fun Kristeni nikan, enikeniti o ba gbaagbo ni a o gba la, ko ba je esintabiasa.
ADURA
Jesu Kristi olufe, mo gbagbo pe iwo ni omo Olorun ti o wa lati gbaaraye la. Nitorinaa, mojewo re (Jesu Kristi) bi Oluwa ati Olugbala mi. Mo fi gbogbo aye mi fun o, emi o sin o, fun gbogbo aye mi. Jowo ko oruko mi sinu iwe iye, ki o si mu mi mura sile fun ipadabo re nigba keji ki emi ye fun igba soke pelu re ni orun. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin
