KO SI ENI TI KO SEENSE PASIPARO
Ayaba Fasti ko ye oko re si, Oba Ahaswerusi, niwaju awon eniyan olokiki, eyi fa wahala baa. Ayaba ko lati jo ati lati fi ewa re han bi oko re se fe. O yeye re, wipe ki Oba maa se tire, ki oun naa maa se t’oun. Nitorina awon afobaje roo loye, won si wa elomiran ropo re. A kowe re wipe ni ojo keje, nigba ti oti-waini mu inu oba dun, o pase fun Mehunmani, Bista, Harbona, Bigta at Abagta, Setari ati karkasi, awon iwefa meje ti njise niwaju Ahaswerusi Oba. Lati mu Fasti ayaba wa siwaju Oba ti oun ti ade oba, lati fi ewa re han awon eniyan, ati awon ijoye nitori arewa obirin ni. Sugbo Fasti ayaba ko lati wa nipa ase Oba lati owo awon iwefa re nitori naa ni oba binu gidigidi, ibinu re si gbina ninu re. (Esteri 1:10 – 12)
EKO
Igberaga nii siwaju iparun. Gbogbo Kristeni ni lati je onirele okan, niwaju Olorun nigba gbogbo. Ki a mase je ki ipo ati agbara bo wa loju. Ki a je eni ti o gba atunse, ki o ye awa omo Olorun pe won lee fi elomiran ropo wa. Eleda ni opolopo eni ti o kun ojuwon, o le se ipaaro ipo enikeni. Nitori eyi, o ye ki gbogbo eniyan wa riri niwaju Olorun, ki a mase je ki igberaga mu wa se si Olorun.
ADURA
Olorun olufe, jowo, ko mi lati je onirele niwaju re. Je ki emi gba imoran ati atunse re, ki emi lee ni iriri igbega re. Jowo gba mi lowo igberaga, nitori yi o yori si iparun. Je ki emi fi aye gba idari Emi mimo re, ki emi le gbe igbe aye asegun ni aye yi, ki nsi je igbadun didara re ni ile alaaye. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
