ISE OKUNKUN SATANI KO NSE FUN IGBA TITI LAI
Idojuko awon asodi si Kristi si awon eniyan mimo ninu ijoba okunkun ko ni je laelae. Olorun yio si fi opin si ise won, yi o si gba won sinu ina orun apadi. Nitorinaa awon eniyan mimo Olorun yi o yayo isegun won, won a si yin Olorunlogo. Bibeli wipe ‘ohun kan ti ibi ite naa jade wa, wipe, e maa yin Olorun wa, eyin iranse re gbogbo, eyin ti o beru re, ati ewe ati agba. Mo si gbo bi enipe ohun opolopo eniyan, ati bi iro omi pupo, ati bi iro aara nlanla, nwi pe Haleluya, nitori Oluwa Olorun wa, Olodumare njoba. E je ki a yo, ki inu wa ki o si dun gidigidi, ki a si fi ogo fun un, nitori pe igbeyawo Odo-Aguntan de, aya re si ti mura tan. (Ifihan 19:5-7).
EKO
A nro gbogbo Kristeni ti o ba ndojuko inunibini ki won mu okan le, nitori won o gba ere lowo Olorun nikehin. Atako/Idojuko Satani si onigbagbo le buru jai, ki o si le gidigidi, won ko ni pe titi. Won yi o di ohun itan laipe ojo. Gbogbo akitiyan eniyan buburu ni a o gba sinu ina orun apadi. Awon omo Olorun ni lati kun fun ayo, pelu ireti pe ayo won wa nitosi. Lati lee duro, a nilati maa gbadura ni ojoojumo, ki a si jowo ara wa sabe idari Emi mimo.
ADURA
Olorun olufe, jowo je ki Emi Mimo mu ese mi duro dede lodo re fun mi ni okun lati bori idanwo, ki nsi bori ni gbogbo ona. Je ki Emi Mimo re ran mi lowo lati lee gbe, igbe aye asegun ni aye, ki emi lee yayo pelu re ni orun rere. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere Amin.
