AISE IRONUPIWADA O LEWU
Olorun ran awon Israeli leti pe Oun yi o fi iya je won fun aironupiwada ese won. Israeli yio jiya ti o ba tesiwaju ninu ese re, sugbon a o bukun won bi won ba ronupiwada ninu ese won. Eleeda se ileri lati yi ibi kuro ti o ye ki o wa sori awon omo re bi won ba lee yipada kuro ninu ona buburu won. Olorun wipe, E funrugbin fun ara yin ni ododo e ka ni aanu, e tu ile yin ti a ko ro, nitori o to akoko lati wa Oluwa, titi yio fi de, ti yio si fi rojo ododo si yin. (Hosia 10:12)
EKO
Awon ijiya Olorun kan wa lori ese omo eniyan. Ibukun Olorun yio tele awon ti nlepa alafia ti won nsin-in ninu otito ati ododo. Olorun yio se idajo awon ti o ntesiwaju ninu ese won. Sugbon Olorun nfe ki gbogbo eniyan yi pada kuro ni ona ibi ati ona buburu won ki Oun baa le bukun won. Gbogbo iye awon ti o ba te Olorun lorun nipa igbe aye iwa mimo yio ri opolopo ibukun, alafia, aseyori gba ninu aye yi ati ni orun pelu.
ADURA
Olorun olufe, mo mo wipe o ni osuwon otito lati san esan fun awon oloododo, ati lati fi iya je awon eniyan buburu. Jowo ro mi ni agbara, ki emi lee gbe igbe aye ti yio te o lorun, ki emi lee je ninu ibukun re ninu aye yi ati ni orun pelu. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
