IRANWO EMI MIMO
Paulu gbadura fun awon Kristeni ki won ni emi isokan. Ki won baa Lee sin Olorun papo pelu okan kan. Paulu gbadura bayi, Nje ki Olorun suuru ati ituni, ki o fi fun yin lati ni inu kan si ara yin gegebi Kristi Jesu. Ki eyin ki o le fi okan kan ati enu kan yin Olorun, Baba Jesu Kristi Oluwa logo (Romu 15:5-6)
EKO
Isokan Kristeni se Pataki, eyi yio mu itesiwaju ati gbigboro ba ipolongo ihinrere. O fee je ko seese lati se eyi larin awon ara, laisi iranlowo Emi mimo. Onigbagbo nilo iranlowo Emi mimo ju ohun gbogbo lo. Emi mimo yio ran wa lowo lati te Olorun lorun ju tite aye lorun ati ife ti ara. O se pataki ki ara-Kristeni wa akoko ti o joju lati wa Oju Olorun, lati gba agbara Emi mimo, ki won si maa sise labe idari re.
ADURA
Olorun olufe jowo se iribomi ti Emi Mimo fun awujo Kristeni. Je ki awon ara boo kuro li ara won, emi temi nikan ati igberaga, ki won wa ni isokan pelu ife. Je ki ife otito ki o wa laarin ara, ki ina ihinrere le tan lati ara won si orile agbaye, ki alaigbagbo le di eni igbala. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
