IFE SE PATAKI
Ife se Pataki, gbogbo eniyan ni o fee. Iye lori ife ni a ko lee fi we ohunkohun amuye miran, Bibeli wipe ‘Omi pupo ko le pana ife bee ni kikun omi ko le gbe lo, bi eniyan fe fi gbogbo oro re fun ife, a o kegan re patapata. (Orin Solomoni 8:7)
EKO
Ife se Pataki si gbogbo eniyan, Olorun pase ki gbogbo eniyan ni ife otito si ara won. O seni li aanu wipe opolopo ni o si ife tunmo, won a ni ohunkohun ti a ba pe ni ife ni lati mu ere fun won, ife kii mo tara re nikan, ife kii se ki a bara wa lopo, ife ki nseke, kii se ojusaju. Oun ni iwa bi Olorun, kii se imotara eni nikan. Olukuluku ni lati se ayewo ohun ti a pe ni ife, ti abajade wa ba kuna ododo Olorun, eyi kii se ife.
ADURA
Olorun olufe, jowo je ki okan mi kun fun ife otito, ti yi o se awon eniyan ni anfani, je ki ihuwasi ife mi ki o yin oruko re logo. Je ki ife mi je aimotara eni nikan, ko mase ojusaju, ko je otito ti o nsi so eso. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
