WIWA OJU OLORUN
Dafidi ati awon omo ogun re padanu ebi won ati ohun ini won sowo ota lati okere wa, won si sekun kikoro. Ko si eni ti o mo ohun ti won iba se bikose Dafidi, o si to Olorun lo fun itoni, Olorun si ran lowo. Bibeli wipe ‘Dafidi ati awon omokunrin si wo ilu, si woo a ti kun un, ati obirin won ati okunrin won ati omobirin won ni a ko ni igbekun lo. Dafidi ati awon eniyan ti o wa lodo re si gbe ohun won soke, won si sunkun titi agbara ko si fun won mo lati sunkun, a si ko awon aya Dafidi mejeeji nigbekun lo. Ahineamu ara Jesreali ati Abigaili aya Nabali ara Karmeli, Dafidi si banuje gidigidi nitoripe awon eniyan naa si nsoro lati so o ni okuta, nitori ti inu gbogbo awon eniyan naa si baje, olukuluku okunrin nitori omo re okunrin ati nitori omo re obirin, sugbon Dafidi mu ara re ni okan le ninu Oluwa Olorun re. dafidi si wi fun Abiatari alufaa omo Ahimeleki pe, emi be o mu efodu fun mi wa nihin-in-yi, Abiatari si mu efodu naa wa fun Dafidi, Dafidi si beere lodo Oluwa wipe ki emi o lepa ogun yi bi? Emi le ba won? O si daa lohun pe, lepa nitori pe ni biba, iwo o ba won, ni gbigba iwo o ri won gba.
(samueli kini 30:3-8)
EKO
Olorun si nsoro yi o si se itoni fun enikeni ti o ba mun ni koko lati wa sodo re fun ijuwe ona ni ohunkohun ti a fe se. A ki yi o doju ti awon ti nwa oju Oluwa, ese won ki yi o ye, nitori na a ro gbogbo eniyan ki a maa woju Olorun ni ojojumo fun itoni ki a ba le di eni ibukun. Lopin re Bibeli wipe ‘A se ilana ese eniyan lati owo Olorun wa, O si se inu didun si ona re (Orin Dafidi 37:23)
ADURA
Olorun olufe jowo fun mi ni ore-ofe lati le maa wa oju re ninu ohun gbogbo ki mba ni aseyori. Je ki ntele idari re bi o se nto mi, mase je ki wahala aye wo mi lorun tie mi o fi gbagbe lati ke pe o fun iranlowo. Je ki nma too wa fun itoni ni gbogbo igbese, ki nsi se aseyori ni oruko re, ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
