JESU TI SEGUN IKU
Jesu Kristi ji dide lehin ojo keta ti a ti sinku re, bi awon obinrin kan ti kun fun iporuru okan ti won unwa oku Jesu ti o sonu, Angeli Olorun yo si won, o si ran won leti nipa bi o ye ki olugbala ji dide nipo oku ki o si wa laaye titi lae. Alaye isale yi so bi o se sele ‘Ni ojo kini ose ni kutukutu owuro won wa si iboji, won unmu turari wa ti won ti pese sile ati awon miran kan pelu won. Won si baa, a ti yi okuta kuro ni enu iboji, nigba ti won wo inu re won ko si ri oku Jesu Oluwa, o si se, bi won ti nse ran-un ran-un kiri niha ibe, kiyesii awon okunrin meji alaso didan duro ti won. Nigba ti eru nba won ti won si dojubole, awon Angeli naa bi won pe eese ti eyin fi unwa alaaye laarin oku? Ko si nihin-in yi sugbon o jinde, e ranti bi o ti wi fun yin nigba ti o wa ni Galili pe a ko le saima fi omo-eniyan le awon eniyan elese lowo, a o si kan an mo agbelebu ni ojo keta yoo si jinde
(Luku 24:1-7) Jesu funra re fi ara han die lara awon omo ehin re lehin ti o jinde, o si ran won leti bi Olorun se seto bi oun o se ji dide lati ipo oku. (Luku 24:13-16, Luku 24:25-27, Luku 24: 26-42)
EKO
Jesu Kristi ji dide lati ipo oku si ile alaaye, Satani yi o di eni itiju lae lae, ota ti sa gbogbo ipa ati agbara re si Jesu sugbon ko lee bori. O lero wipe nipa iku Jesu a ko ni gburo re moo, sugbon Satani pofo lori Jesu, iku ko le di Jesu mu fun igba pipe sugbon o jinde o si wa laaye titi lae. Bakan naa ajinde Jesu ti pese iye ainipekun fun awon omo-ehin re. enikeni ti o ba jewo Jesu ni Oluwa ti o si gba a ni olugbala re, yi o jinde ninu iku akoko lati ma gbe titi lae pelu Olorun. Iku ati ipo oku ko ni agbara lori kristieni. Kristi yi o ji awon onigbagbo dide nikehin ojo yi o si fun won ni kokoro iye ainipekun. Haleluya
ADURA
E yin Olorun, Jesu ji dide ninu oku, iku Jesu ti fun mi ni iye ayeraye oju ti Satani ogo ni fun Olorun. Emi je onigbagbo ninu Jesu Kristi, mo si je alabapin ninu ajinde, nigba ti mo je atunbi kristieni, ese ati iku ko ni agbara lori mi mo. Jesu Kristi ni Oluwa ati olugbala mi, kiyesii un o maa gbe ninu ayo ati Alafia. Un o sii wasuu Jesu Kristi fun awon ore mi, aladugbo mi ati agbaye lae. Haleluya, Jesu joba titi aye. Amin.
