TESIWAJU LATI MAA LO IGBAGBO RE NINU OLORUN
Kalebu gba ere igbekele re si Olorun nigba ti awon to kun ni ijakule, kiki Kalebu ati Josua ni won fi igbagbo ninu. Oluwa han nigba ti a ran awon mejila lati loo se amin ile Kenani. Awon yoku fi ara won we elenga niwaju omiran, won yepere agbara Olorun lati gba won. Nitori na Olorun se leri lati bu ola fun Kalebu (Numeri 14:24). Ki ise kiki pe Kalebu fi igbagbo han ni ipaala Kenani nikan, o te siwaju ninu igbagbo nla titi di ojo arugbo. Ni bi marun le ni ogorun odun. Kalebu to Josua lo lati beere ipin tire ninu ile awon omiran. O to Josua wa, o si wipe ‘Eni ogoji odun ni mi nigba ti Mose iranse Oluwa ran mi lati kadesi-barnea lo sami ile naa, mo si mu ihin fun un wa gege bi o ti wa ni okan mi. sugbon awon arakunrin mi ti o goke lo ja awon eniyan ni aya, sugbon emi to Oluwa Olorun mi leyin patapata. Mose si bura ni ojo naa wipe nitooto ile ti ese re ti te nni, ile-ini re ni yoo je, ati ti awon omo re lae lae, nitori ti iwo ti Oluwa Olorun mi leyin patapata. Nje nisisiyi, kiyesii Oluwa dami si gege bi o ti wi, lati odun marun-lelogogi yii wa lati igba ti Oluwa ti so oro yi fun mose, nigba ti Isreali nrin kiri ni aginju, si kiyesii nisisiyi, emi di eni arundinlaadorun odun ni oni. Sibe emi ni agbara ni oni gege bi mo ti ni ni ojo ti mose ran mi lo, gege bi agbara mi ti ri nigbana ani bee ni agbara mi ri nisisiyi, fun ogun, ati lati jade ati lati wole. Nje nitori naa fi oko yi fun mi, eyi ti Oluwa wi ni ojo naa, nitori ti iwo gbo ni ojo naa bi awon omo Anaki ti wi nibe, ati ilu ti o tobi, ti o si se olodi, boya Oluwa yoo wa pelu mi, emi o si le won jade gege bi Oluwa ti wi. Josua si sure fun un, o si fi Hebroni fun Kalebu omo Jefunne ni ile-ini. Nitori naa Hebroni di ile-ini Kalebu omo Jefunne ti Kenissi titi di oni-oloni, nitori ti oto Oluwa Olorun Isreali leyin patapata. oruko Hebroni laelae ri a maa je Kiriati-arba; Arba je eniyan nla kan ninu awon omo Anaki. Ile naa si simi lowo ogun. (JOSUA14:7-15).
EKO
Enikeni ti o ba ni igbagbo nla ninu Olorun, oju ko ni ti iru eni be labe bo se le je. Olorun ti o ni ki a gba oun gbo ko ni ko wa si le. O le dabi aye ti dori kodo fun eni to ni igbagbo sugbon niwon igba ti igbagbo re wa ninu Olorun, iji yi o dawo duro laipe ojo, o o si yan jade pelu isegun. Ko si idiwon ni lilo igbagbo wa fun ini wa lojojumo aye wa (A le lo igbagbo lati bori ohunkohnu ti o le doju ko igbe aye wa) ni oro kan, a le fi igbagbo wa ninu Olorun san gbese, se iwosan, riri ise, igbeyawo, omo bibi, okowo sise ati nkan miran. Nitori na gbogbo eni ti o ba nkepe oruko Olorun, ye ki o fi igbagbo re si ise lati segun ni gbogbo ona laye. Awon ti o ni igbagbo ni oju won yi o ma dan yala nigba ojo ati orun reran fun ola oruko Olorun.
ADURA
Olorun olufe jowo ran mi lowo kin le lo igbagbo mi ni gbogbo ona lati ni isegun ki nsi yin oruko re. ran mi lowo ki igbagbo mi mase ye ni akoko ipenija, je ki igbagbo mi le bi okuta, ki o si jewo agbara igbala re. nigba inira je kin le ma wipe ‘Olorun ti mo nsin lojojumo o to, yi o si gba mi ninu isoro akoko yi. Jowo je kin wa si agbo awon eniyan lati jeri si didara re, ki awon eniyan le ru igbagbo won soke loju igbenija won. Ni oruko Jesu Kristi mo fe ni igbagbo ti o duro ninu re. Amin.
