FI IFE RE HAN SI OLORUN NIPA FIFI IFE HAN SI OMOLAKEJI RE
Ojogbon agbejoro kan fe fi esun kan Jesu Kristi nipa igbe aye iwa mimo, fun amuye lati le jogun ijoba. Olorun Okunrin na bi Jesu leere pe ‘Olukoni, kin ni emi o se ki emi le jogun iye ainipekun’ (LUKU 10:25) Jesu so fun ki iwo ki o fi gbogbo aye re ati gbogbo okan re, ati gbogbo agbara re, ati gbogbo inu re fe Oluwa Olorun re, ati enikeji re bi ara re. o si wi fun un pe, iwo dahun rere, se eyi, iwo o si ye.sugbon o nfe lati da ara re lare, o wi fun Jesu pe, ta ha si ni enikeji mi? Jesu si dahun o wipe, Okunrin nkan nti Jerusalemu sokale lo si Jeriko, o si bo si owo awon olosa, ti won gba a ni aso, won saa logbe, won si fii sile lo ni aipa ni apatan, ni alabapade li alufa kan si nsokale lo lona na, nigbati o si ri i , o koja lo niha keji. Bee na si ni omo lefi kan pelu, nigbati o de ibe, ti o si ri i, o koja lo niha keji. Sugbon ara Samaria kan, bi o ti nre ajo, o de ibi ti o gbe wa, nigbati o rii, aanu se e. o si to o lo, o si dii logbe o da ororo ati oti-waini sii, o si gbe le ori eranko ti oun funra re, o si mu wa si ile-ero, o sin se itoju re, nigbati o si lo ni ijo keji, o fi owo ide meji fun olori ile ero, o si wi fun un pe maa toju re, ohunkohun ti iwo ba si na kun u, nigba ti mo ba pada de, emi o san an fun o. ninu awon meteta won yi, ta ni iwo ro pe ise enikeji eni ti o bo si owo awon olosa? O si dahun wipe eni ti o saanu fun u ni. Jesu si wi fun u pe, lo, ki iwo ki o si se bee gege.
(LUKU 10:27-37).
EKO
Enikeni ti o ba fe jogun ijoba Olorun ni lati fi ife pipe sinu ise ki o si gbe igbe aye ti o yato. Afihan ife otito ati pipe si Olorun ni lati han nipa nini ife si awon eniyan layika wa. A ko le so wipe a fe Olorun ti ako ri, ki a korira awon eniyan ti a ri. Olorun nfe ki a huwa to dara si awon eniyan. Anfani nbe ninu ife pipe onigbagbo si ara won. Yi o bukun eni ti o ri gba, yi o si tun faa si odo Olorun, ti yi o si mu ki ijoba Olorun maa po sii. Yi o si mu ki inu wa dun, nipa gbigboran si ase Olorun. Olorun yi o san pada fun omo to ba gboran nipa bibukun fun. Jehofa yi o rojo ibukun re sori gbogbo awon ti o ba gboran si ofin re ti o si ni ife tooto.
Fun alaye sii, Jesu so itan arakunrin Samaria lati da adajo ti o ndara re lare. Eyi tii se IFE( LUKU 10:25-37) A le so pe ohun ti Olorun yi o lo bi osuwon Kristieni le maaje nipa oye esin tabi akitiyan ninu ise iranse. Eni ti a le pe ni ‘Kristieni to dara’ nilati je eni ti o sun mo awon eniyan, ti o mo bi won se ri, ti o si sa gbogbo ipa lati ran won lowo, bi oun ti ni agbara.
ADURA
Olorun olufe jowo se mi ni Kristieni ti o feran awon eniyan pelu aya funfun. Ran mi lowo kinmase mo tara mi nikan. Se mi ni oluranlowo won, kin mase dakun isoro won. Se mi ni asaju re tooto ni aye, kinsi sin o bo ti ye, ki emi le peye fun ekun rere ibukun ijoba re. ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
