SANBALLATI ATI TOBAYA
Olori olote meji (Sanballati ati Tobaya) gbiyanju lati dawo Nehemiah duro ni atunko odi Jerusalem, sugbon won pofo. Awon ota yeye Nehemiah ati awon alabasise ti won sa gbogbo agbara won lati se atunko ilu Olorun. Bibeli salaye nipa atako lati owo Sanballati ati Tobaya “o si se, nigba ti Sanballati gbo pe awa mo odi naa, inu re ru, o si binu pupo, o si gan awon ara Juda. O si so niwaju awon arakunrin re ati awon omo-ogun Samaria pe, kin ni awon alailera Juda wonyi nse yii? Won o ha da wa fun ara won bi, won o ha rubo? Won o ha se asepari ni ijokan? Won o ha mu okuta ti a ti sun lati inu okiti soji? Tobaya ara Ammoni si wa ni eti odo re, o si wipe eyi ti won mo gidi bi kolokolo ba gun un yoo tile wo odi okuta won lule. (Nehemiah 4:1-3). Nehemiah ati awon eniyan re pinnu lati se atunko odi Jerusalemu.
Won gbadura lori otan won, won si dabobo ara won. Nehemiah ati awon eniyan re gbadura wipe ‘Gbo Olorun wa, nitori ti awa di eni egan ki iwo ki o si da egan won si ori ara won, ki o si fi won fun ikogun ni ile igbekun. Ki o ma si bo irekoja won, ma si je ki a we ese won nu kuro niwaju re, nitori ti won bi o ninu niwaju awon omole. Nitori naa ni mo yan awon eniyan si ibi ti o rele leyin odi, ati si ibi gbangba, mo tile yan awon eniyan gege bi dile odi, ati si ibi gbangba, mo tile yan awon eniayn gege bi idile won, pelu ida won, oko won ati orun won. Mo si wo, mo si dide, mo si wi fun awon ijoye, ati fun eru won ba yi wipe, e ranti Oluwa ti o tobi, ti o si ni eru, ki e si ja fun awon arakunrin yin, awon omokunrin yin ati awon omobinrin yin, awon aya yin ati ile yin. (Nehemiah 4:4-5, Nehemiah 4:13-14)
EKO
Idojuko fun Kristeni bi ti Samballati ati Tobiah maa nwa nigba miran lati fa ijakule fun awon omo Olorun. Idojuko le je nipa ti ara tabi nipa tie mi, ero ati ete won ni lati mu omo Olorun gbonjege iduro won pelu Olorun. Awon ota wonyi ko ba wa ro ero ti o dara. Nitori naa awa omo Olorun nilati kiyesara, ki ero ota mase wa si imuse ninu ise iranse wa. Onigbagbo ni lati da arekereke ota mo, ki won si da won duro. Ki a sa gbogbo ipa ninu adura ati awe lati pa ota lenu mo. Ki a mase dagara lati gbe igbese ti o ye lati da awon ota duro. Ni Pataki onigbagbo ni lati ni igbekele ninu Olorun. Ki a ni idaniloju pe Olorun wa ni arowoto wa, lati ran wa lowo lati bori awon ota wa.
ADURA
Olorun olufe jowo yeye ota ti o ba fe se idiwo mi lati sin o. Je ki iran Sanballati ati Tobaya parun ninu aye mi. Mo gba ore-ofe re lati duro ni igboya, kin le tesiwaju lati maa sin o ni emi ati ni otito. Jowo je ki eri re maa wa ninu aye mi. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
