ITANJE IGBAKEYIN
Johanu ri ifihan pe Satani yi o ran awon emi aimo jade lopolopo ni akoko opin aye. Awon asoju Satani yi o so oro ijinle, won yi o se opolopo ise iyanu lati tan eniyan je. Enikeni ti o ba gbagbo ninu emi eke wonyi, yi o da ara re lebi nikehin. Jesu Kristi kilo fun gbogbo eniyan lati kiyesara, ki won je mimo, ki Satani mase tan won je. A ko isipaya Johanu bayii mo si ri awon emi aimo meta bi opolo, won ti enu dragoni naa ati eni eranko naa ati eni wooli eke naa jade wa. Nitori emi esu ni won, ti n se ise iyanu, awon tin jade lo sodo awon oba gbogbo ile aye, lati gba won jo si ogun ojo nla Olorun Olodumare, kiyesi, mo nbo bi ole, ibukun ni fun eni ti nsona, ti o sin pa aso re mo, ki o ma baa rin ni ihooho, won a si ri tiju re. (Ifihan 16:13-15).
EKO
Dajudaju Satani yi o ran awon demoni jade lati tan eniyan je ni opin aye. Bibeli sekilo ki a kiyesara, ki a mase bo sinu pampe Satani. Enikeni ti o ba ko si ewon-ode Satani, yio jiya opolopo isofo. Gbogbo awon ti Satani ba segun ni yi o lo si orun ina apadi. Ogun kii pa aro ti o ba gbon. Gbogbo eniyan ni lati gbiyanju lati mo otito. Ki a keko bibeli/oro Olorun, ki a mase gbagbo ninu eko tabi asotele ti ko ni atilehin bibeli. Onigbagbo nilati kun fun adura, ki a beere agbara Olorun nipase Emi mimo ki a le kojuwon niwaju Olorun. Ki o mase je eni idojuti ni ojo idajo Oluwa.
ADURA
Olorun olufe jowo gba okan mi kuro lowo asodi si Kristi ti Satani yi o ran lati tan araye je. Ran mi lowo lati mo otito, se aajo otito, ki emi si huwa otito. Mase je ki emi di eni ti Satani segun, ran mi lowo lati le bori ki nsi lo si orun rere lehin irin ajo mi ni aye yi. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
