OPIN OHUN GBOGBO
Laipe ojo, Olorun yi o fi opin si aye yi. Yi o mu gbogbo okan ati emi wa si ibi idajo re. Olorun yi o se abewo ise olukaluku, yi o si san ere fun won bi ise won ba se ri. Satani ati awon atele re ni yi o da sinu ina orun apadi. Eleda yi o kede aseyege awon atele Jesu Kristi, nitori won ti jewo igbagbo won ninu re. Awon atele Jesu Kristi ni a o fun ni aye laelae ni orun nibi ti won yio wa ni Alafia ati idera. Bibeli wipe, Mo si ri ite funfun nla kan ati eni ti o jokoo lori re, niwaju eni ti aye ati orun fo lo, a ko si ri aaye fun won mo. Mo si ri awon oku, ati ewe ati agba, won duro niwaju ite, a si si awon iwe sile, a si si awon iwe miran kan sile ti I se iwe iye, a si se idajo fun awon oku lati inu ohun ti a ko sinu awon iwe naa gege bi ise won. Okun si jowo awon oku tin be ninu re lowo, ati iku ati ipo-oku si ju oku ti o wa ninu re lowo, a si se idajo won, olukuluku gege bi ise won. Ati iku ati ipo-oku, ni a si so sinu adagun ina. Eyi ni iku keji. Bi a ba si ri enikeni ti a ko ko oruko re sinu iwe iye, a so o sinu adagun ina. (Ifihan 20:11-15)
EKO
Ireti pipe ojo idajo Olorun ninu aye ti sunmole, awon olotito atele Jesu Kristi ni a o fun ni ebun ayeraye ni orun. Satani ati awon angeli re ti won subu ni won yio gba ebun ina orun apadi. Awon eniyan ti won ko lati gba Jesu Kristi ni Oluwa ati Olugbala won, yio lo si ina orun apadi. Won yio maa jiya ninu ina orun apadi titi laelae. (Orun ina apadi kun fun ina Olorun ti kii ku, o n jo pelu ina ati sufunu. (Ifihan 21:8). Olorun oloore-ofe setan lati dariji elese ti o ba ronupiwada. Yi o dariji enikeni ti o ba ronupiwada ti o si jewo Jesu Kristi ni oluwa. O wa se pataki ki gbogbo eniyan gbe igbese jijewo Jesu Kristi ni Oluwa ati Olugbala won, ki o to peju. Ijafara ni ewu, nitori ko si eni ti o mo igba ti iku lee de (tabi igbati igbasoke awon eni mimo lee de).
ADURA
Olorun olufe, emi ko fe lo si orun ina apadi, sugbon mo fe lo si orun rere. Jowo ka mi ye fun orun mo mo wipe igbagbo ninu Jesu Kristi ni iwe eri si orun, nitori naa mo jewo igbagbo mi ninu Jesu Kristi. Mo gbagbo pe oun ni Olugbala gbogbo araye mo si gbaa gege bi Oluwa ati Olugbala mi. Jowo dari ese mi ji mi, ki o si fun mi ni okun lati sin o titi de opin. Jowo ko oruko mi sinu iwe iye, ki emi si ye fun ijoba re ainipekun ni oruko Jesu Kristi Oluwa mi ni mo gbadura ti mo si jewo igbagbo mi Amin.
