OLORUN YIO MA JE ABOO WA
Dafidi ri iponju o si kepe Olorun fun iranlowo, o mo wipe Olorun nikan lo ni gbogbo agbara ti o le gba oun la patapata. Dafidi gba adura o wipe ‘Ran mi lowo Oluwa, Olorun mi, gba mi gege bi aanu re, ki won ki o le mo pe owo re ni eyi, pe iwo Oluwa ni o see, je ki won o maa gegun-un sugbon iwo maa sure, nigba ti won ba dide ki oju ki o tiwon sugbon iranse re yio yo, je ki a fi itiju wo awon ota mi ni aso ki won ki o si fi idarudapo won bo ara, bi eni pe ewu.
(Orin Dafidi 109:26-29)
EKO
Olorun ni abo nla ni akoko ini, yi o pese yio si dabobo awon omo re ti o ba ke pee. Bi o ti wu ki ogun le to Olorun yi o bii wo lule, yi o yi egun pada si ibukun, yi o yi inilara pada si igbega. A ro awon omo Olorun ki won gbona ninu adura ki won ni igbekele ninu Olorun, ki won baa le je ni kikun anfani Olorun.
ADURA
Olorun olufe, mo mo wipe iwo ni abo nla fun awon ti o gbeke le o, nitori naa mo kepe o ki o gbeja mi lori awon ota mi, bi awon ota mi subu si mu mi bori won. Je ki Satani ati awon iranse re subu sinu ijiroro ibi won, mo be o ki o bukun mi, dabobo mi si fun mi ni ifokan bale ti o koja oye eniyan. Je ki nma lo gbogbo iyoku aye mi ninu isegun. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
