AGBODO SO ESO RERE
Jesu Kristi so fun awon omo ehin re wipe ki won waasu ihinrere, ki won si so eso fun ijoba Olorun. Enikeni ti ko ba so eso ko ni si ere fun un ni orun sugbon a o da iru eni bee lejo, Jesu Kristi wipe ‘Emi ni ajara tooto, baba mi si ni olusogba gbogbo eka ninu mi ti ko ba so eso, oun ni ao mu kuro, gbogbo eka ti o ba so eso oun a wee mo, ki o le so eso sii.
(Johanu 15:1-2)
EKO
Bi o je ti Jesu Kristi, ko si awawi ni orun lati je alaileso kristieni. Gbogbo kristieni nilati ni eso rere fun ijoba Olorun. Awa atele Jesu Kristi ni lati ni igboya lati doju ko ohunkohun ti o ba pe igbagbo wa nija, ko si kristieni ti o ye ki o faye gba ijegaba niwon ti o nilati waasu ihinrere. Wiwaasu ihinrere se pataki, o je ase Olorun, gbogbo kristieni ni lati see. Bibeli fi ye wape ‘Nitori naa mo pase fun o niwaju Olorun ati Kristi Jesu eni ti yoo se idajo alaye ati oku, ati nitori ifarahan re ati ijoba re, waasu oro naa, se aisinmi ni akoko ti o wo ati akoko ti ko wo, ba niwi, se itoni, gba-ni niyanju pelu ipamora, ati eko gbogbo. Nitori pe igba yoo de ti won ki yoo le gba eko ti o ye kooro sugbon bi won ti je eni ti eti nrin won, o lo ko oluko jo fun ara won ninu ifekufe ara won, won o si yi eti won pada kuro ninu otito, won o si yi pada si itan asan sugbon maa se pele ninu ohun gbogbo, maa fara da iponju, se ise ajinyinrere, se ise iranse re lasepe. (Timotiu Keji 4:1-5)
ADURA
Jesu Kristi olufe, jowo ran mi lowo lati se dede ninu ise iranse mi, ran mi lowo lati waasu ihinrere, ki nsi mu eso wa sinu ijoba re. fun mi ni ore-ofe lati le fara da gbogbo inunibini, fun mi ni agbara Emi-Mimo lati le paati gbogbo awawi, ki nja fafa ninu ise isin mi. Fun mi ni ore-ofe ifami-ororo yan lati je ohun elo ti yio din ijoba Satani ku, ti yi o mu ki ijoba re maa po sii. Je ki emi sin o ni aye, ki emi le ye fun opolopo ebun ti orun. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
