OLORUN YIO GBEJA ORUKO RE
A ro kristieni lati bu ola ti o ye fun Olorun, a ko ni lati mu pelu owo yepere a ni lati fun ni ohun gbogbo, ki o le ni inu didun si wa pelu igbe aye otito. Eleda seto opolopo ijiya fun eyi keyi ninu awon omo re ti o ba yese kuro ninu otito, a ti koo wipe ‘Olorun njowu, Oluwa si ngbesan, Oluwa ngbesan o si kun fun ibinu, Oluwa ngbesan ni ara awon ota re o si fi ibinu de awon ota re. oluwa lora lati binu, o si tobi ni agbara, ni didasile ki yoo da eniyan buburu sile, Oluwa ni ona re ninu aaja ati ninu iji, awosanma si ni ekuru ese re, o ba okun wi o si mu ki o gbe, o si so gbogbo odo di gbigbe, Basani di alailera ati Karmeli, itana Lebanoni si ro. Awon oke-nla mi nitori re ati awon oke kekeeke di yiyo, ile aye si jona niwaju re ani aye ati gbogbo awon ti ngbe inu re, tani o le duro niwaju ibinu re? ta ni o si le duro gba gbigbona ibinu re? a da ibinu re jade bi ina, oun ni o si fo awon apata. Rere ni Oluwa, aabo ni ojo iponju, oun si mo awon ti o gbekele, sugbon ikun omi akunrekoja ni oun fi se iparun ibe naa de opin, okunkun yoo si ma lepa awon ota re.
(Nahumu 1:2-8)
EKO
Didara Olorun wa lekun rere fun awon omo re, yi o sa gbogbo ipa re lati ja fun oruko re ninu aye won. Bibeli kilo fun wa lati sora bi a se nhuwa pelu Olorun, a ko gbudo si awon anfani re lo a nilati mo riri re nipa gbigbe igbe aye iwa mimo, ti a ba se ohun ti oto ti a si sin daradara, eleda pelu afikun didara re ninu aye wa, yi o se wa loso bi aba bola fun.
ADURA
Olorun olufe, jowo fun mi ni ore-ofe lati le maarin pelu re ni gbogbo akoko, mase je kin mu awon anfani re pelu owo yepere. Je kin mo riri re, ran mi lowo lati gbe igbe aye to peye niwaju re, ki o si so di pupo awon anfani re ninu aye mi. ki emi le ma jeri didara re ni gbogbo ojo aye mi, ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
