B’OWO FUN OLUWA ATI AWON IRANSE RE
Inu Olorun ko dun si omobinrin ti o fi Dafidi oba se yeye nigba ti o njo ti o si nyin Olorun, Dafidi ti se ase nla, o si ti pe gbogbo eniyan lati wa wo bi oun se maa jo niwaju apoti eri majemu Olorun, sugbon iyawo Dafidi (Mikali) Kegan re, o si fi se yeye. O Gbagbo pe oba ti re ara re sile nipa sise iru ase bee ‘Mikali dojuko Dafidi o s iwi fun pe, bi o ti se ohun ogo to lonii fun oba Isreali ti o bo ara re sile lonii loju awon iransebirin awon iranse re, gege bi okan ninu awon eniyan asan ti bora re sile (Samueli keji 6:20) sugbon Olorun ati Dafidi binu si ihuwasi Mikali nitorina o yagan. Bibeli wipe ‘Niwaju Oluwa ni eni ti o yan mi fe ju baba re lo ati ju gbogbo idile re lo, lati fi emi se olori awon eniyan Oluwa ani lori Isreali, emi o si sire niwaju Oluwa, emi o si tun re ara mi sile ju bee lo, emi o si se alainiyin loju ara mi ati loju awon iransebirin wonni ti ti iwo wi, lodo won naa ni emi o si ni ogo. Mikali omo Saulu ko si bi omo titi o fi di ojo iku re.
(Samueli keji 6:21-23)
EKO
A ko gbudo gan Olorun ati awon iranse re, Olorun se Pataki ju ki a Kegan re, awon iranse re si je eni owo. Ko ye ki o ya wa lenu ti a ba ri ifaraya Olorun si awon alaigbagbo eniyan ti won ba siwahu si Olorun ati awon iranse re, gbogbo eniyan ni lati kiyesara ki a ma ba gba ibinu Olorun. Jehofa ni ibukun fun awon ti o ba bu ola fun ti o si bowo fun awon iranse re, enikeni ti o ba mo titobi Olorun ti o si bowo fun awon iranse re, yio ri ibukun gba.
ADURA
Oluwa olufe, o te mi lorun lati gba ibukun die ju egan pupo, nitori naa mo pinu lati bu ola fun o, ki nsi bowo fun awon iranse re ki emi le se rere. Mase je kin mu o tabi awon iranse re pelu owo yepere, sugbon kin bu ola fun eni ti o ba ye, ki emi le se rere ni ile alaaye. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
