JESU NIKAN NI ONA SI IYE AINIPEKUN
Paulu ni iyipada kuro ni sise inunibini si ijo, o wa di ara ijo, o ni iriri pelu Olorun o wa di kristieni. Paulu salaye itan aye re o wipe ‘Mo si se inunibini si ona yii titi o fi de iku, mo nde, mo si nfi won sinu tuubu ati okunrin ati obirin, bi olori alufaa pelu ti je mi ni eri ati gbogbo ajo awon alagba, lowo awon eni ti mo si gba iwe lo sodo awon arakunrin ti mo si lo si Damasku lati mu awon ti o wa nibe ni dide wa si Jerusalemu lati je won niya. O si se, bi emi ti nlo ti mo si sunmo eti Damasku niwon ojokanri, ni ojiji imole nla mo ti orun wa yi mi ka, mo si subu lule mo si ngbo ohun kan ti o wi fun mi pe, Saulu, Saulu, eese ti iwo fi nse inunibini si mi? emi si dahun wipe iwo ta ni Oluwa? O siwi fun mi pe, emi Jesu ti Nasareti ni, eni ti iwo nse inunibini si.
(Awon Aposteli 22:4-8)
EKO
Olorun maa nfe nigba gbogbo lati ri elese ti o ronupiwada kuro ninu ese re, ti o gba igbala ti a seto nipa omo re Jesu Kristi. Igbala Jesu Kristi wa fun gbogbo eniyan, o se iyebiye sugbon ofe ni, Jesu yio gba enikeni ti o ba too wa bi o ti wu ki ese eniyan buru to, yio we moo. Yio se atuse si ohun ti o baje, yio si se amupada ti o rewa si ojo iwaju eni ti o ba too wa, ko si esin ti o je idena, awon elesin miran le to Jesu Kristi wa. Yio gba enikeni ti o ba too wa iba se Musulumu, Budusitu, Hindu, Alasa Abalaye tabi esin miran. Ko si ona abayo miran lati ni igbala ayeraye bikose nipase Jesu Kristi, gbogbo eniyan ti o wa ninu esin miran ni a ro ki won se ayipada ona won, kii won di omo lehin Jesu Kristi. Gbogbo eniyan nilati jewo Jesu Kristi gegebi Oluwa ki won le di eni igbala, Jesu Kristi wipe, Emi ni ona ati otito ati iye ko si enikeni ti o le wa sodo Baba bi ko se nipase mi (Johanu 14:6)
ADURA
Mo ti seleri lati tele Jesu, Mo ti seleri lati tele Jesu, Mo ti seleri lati tele Jesu, ko si ayipada, ko si ayipada. Loni (Da oruko re) jewo Jesu Kristi ni Oluwa, mo jewo ese mi, mo si ronupiwada, mo yonda gbogbo igbe aye mi fun Jesu Kristi, emi o sin o titi igba aye mi, emi koni dese mo, nko ba Satani tayo mo, igbe aye mi je ti Jesu Kristi lati oni lo titi lae. Amin.
