OLORUN FERAN IRONUPIWADA
Ise ironupiwada kii se ami ojo, o je ami jije olotito si Olorun alaaye, olotito ati onirele eniyan kii tiju lati ronupiwada kuro ninu ese won. Won ko lati maa yo ninu ese won sugbon won ronupiwada, awon ti o ronupiwada ni ireti ninu Olorun lati fun won ni okan lati bori idanwo ti ojo iwaju. Woli jewo iduro re pelu Olorun, o se ijewo ireti isegun re ni ojo iwaju. Woli na wipe ‘Ma yo mi iwo ota mi, nigba ti mo ba subu emi o dide, nigba ti mo ba jokoo ni okunkun Oluwa yi o je imole fun mi. emi o ru ibinu Oluwa nitori emi ti dese sii titi yoo fi gba ejo mi ro, ti yoo si se idajo mi, yio mu mi wa si imole, emi o si ri ododo re.
(Mika 7:8-9)
EKO
Olorun feran awon eniyan ti won re ara won sile ti won si ronupiwada kuro ninu ese won, o nani igboya won lati ko ibi sile won si lepa ododo. Bibeli wipe ‘Olorun ko oju ija si awon agberaga sugbon o fi oore-ofe fun awon onirele okan. (Jakobu4:6) Nitori naa awa omo Olorun nilati see ni pataki ironupiwada kuro ninu ese, eyikeyi ninu omo Olorun ti o ba subu sinu ese nilati ronupiwada ki o le ri idariji Olorun gba. Eledaa je baba onife, yi o dariji, yi o si fa elese ti o ronupiwada mora.
ADURA
Olorun olufe, mo se ikedun fun awon ese mi, mo loye pe olufe ati Olorun ti ndari jinni ni o, nitori naa mo bebe ki o dariji gbogbo ese mi, jowo daa pada fun mi ayo igbala mi, je ki Emi-Mimo re fun mi ni okun lati le bori idanwo awon ota, jowo fun mi ni agbara lati wa ni ododo ki emi si maa se akiyesi ofin re. Jowo fi mi lese mule ki nle gba ibukun re ni aye ati ni orun pelu. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
