A PE AWON KRISTENI LATI KEDE IHINRERE
Paulu fi imo segun awon ota re nipa fifi Bibeli se atinlehin ariyanjiyan re. Egbe Juu meji (Farisi ati awon Sadusi) darapo lati se inunibini si ise iranse re, iporuru okan de baa won nigba ti Paulu je ko ye won pe, apa kan ninu won gbagbo ninu esin ti won fi kan an (awon Farisi gbagbo ni nu ajinde sugbon awon Sadusi ko gbagbo ninu ajinde) Paulu, adajo ti o di oniwaasu fi imo ijinle re han, Bibeli wipe ‘Sugbon nigba ti Pa5ulu sakiyesi pe apakan won je Sadusi, apakan si je Farisi o kigbe ni igbimo pe ara Farisi ni emi, omo Farisi, nitori ireti ati ajinde oku ni a se ba mi wijo. Nigba ti o si tiwi eyi, ipinya de laarin awon Farisi ati awon Sadusi, ajo si pin si meji. Nitori ti awon Sadusi wipe ko si ajinde tabi Angeli tabi emi sugbon awon Farisi jewo mejeeji. O si di ariwo nla, ninu awon akowe ti o wa ni apa ti awon Farisi dide won nja wipe, awa ko ri ohun buburu kan lara okunrin yii, ki si ni bi emi kan tabi Angeli kan ni o baa soro.
(Awon Aposteli 23:6-9)
EKO
Awa kristieni kii se ope, sugbon a ni imo nipa fifi ogo Olorun han. Awon onigbagbo ni ebun abinibi ati imo lati waasu ihinrere nibikibi ti a ba lo, awon imo wa a nilati loo lati fa awon eniyan wa sodo Olorun. Eleda tipe wa, o si ti ko wa labe orisirisi akoko ati igba, o ti da wa si orisirisi ikeko ki a le ni imo ati oye ti o peye ti a nilo fun itan kale ihinrere, gbogbo kristieni lo ni ipa ati agbara kan ti a le je alatilehin akoko kikede ihinrere. Ko si awawi kan fun kristieni pe aini ohun kan ni ko se waasu ihinrere, anro kristieni ni gbogbo ise won, ki won mu eyi ti o dara ju fun Oluwa. Awon onise akanse bi adajo, dokita, onimo ijinke, kolekole, agbebi, onimo ogun oyinbo, onirohin, kapenta, onimo isiro owo, mekaniki, omo-odo atulese, asona, akowe, oloselu, akowe oga ati beebe lo. Gbogbo eniyan ni lati dide si wiwaasu ihinrere Jesu Kristi lai da ibi kan si, a nilati waasu fun gbogbo eniyan olorisirisiasa ati igbagbo won. Bi a ba gboran, ijonba Satani yi o di ahoro, ijoba Olorun yi o ma posi.
ADURA
Olrun olufe, jowo se mi ni ohun elo ola fun o, fun mi ni agbara lati le lo ebun abinibi (ebun mi ati ebun abinibi) fun titan ihinrere kale. Jowo lo mi lati le mu opolopo wa sinu ijoba re, mo si gbadura fun awon kristieni elegbe mi jake jado agbaye, fun won ni igboya lati te siwaju ninu wiwaasu ihinrere. Je ki awon ara tesiwaju wiwaasu ihinrere ki awon eniyan le bo ninu ijiya orun apadi, ki won si ye fun orun rere, je ki itiju de ba Satani, ki ogo ye oruko re nipa wiwaasu bo ti to ati bo ti ye. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
