KIKO OUN ATIJO SILE
Manase oba Juda se ijafara nipa Olorun sugbon o dojuko bibo orisa. O gbe iborisa soke, o fi omo re se irubo (bi irubo eniyan) o si se atileyin ise buburu bi aje, oso, biba oku soro. Bibeli ko akosile nipa Manase oba ‘O si te pepe pelu ni ile Oluwa, ni ti eyi ti Oluwa ti so pe ni Jerusalemu ni oruko mi yoo wa laelae, o si te pepe fun gbogbo ogun orun ni agbala mejeeji ile Oluwa. O si mu ki awon omo re ki o koja laarin ina afonifoji omo Hinnomu ati pelu o nse akiyesi afose, o si nlo alupayida, o si nse aje, o si nba oku lo ati pelu oso, o se buburu pupo ni oju Oluwa lati mu un binu. O si gbe ere gbigbe kale, ere ti o ti ya sinu ile Olorun, ni ti eyi ti Olorun ti so fun Dafidi ati Solomoni omo re pe, ninu ile yii ati ni Jerusalemu ti emi ti yan ninu gbogbo eya Isreali, ni emi o fi oruko mi si laelae. Beeni emi ki yoo si ese Isreali mo kuro ni ile naa ti emi ti yan fun awon baba yin, kiki bi won ba se akiyesi lati se gbogbo eyi ti emi ti pa ni ase fun won, gege bi gbogbo ofin ati ase ati ilana lati owo Mose wa. Bee ni Manase mu ki Juda ati awon ti ngbe Jerusalemu ki o yapa ati lati se buburu ju awon orile-ede lo, awon eni ti Oluwa parun niwaju awon omo Isreali. (Kronika keji 33:4-9) Olorun fiya je Manase oba fun ise buburu ti o se, awon ota bori re, won si ko ni igbekun ati eru lo si Babiloni. O si se nikehin, oba ronupiwada Olorun si dari ese re jii, a ko wipe ‘Nigba ti o si wa ninu wahala, o ba Oluwa Olorun re, o si re ara re sile gidigidi niwaju Olorun awon baba re
(Kronika keji 33:12) Olorun gba Manase pada o si fun ni anfani lati se atunse ibi ti o ti baje.
EKO
Olorun yi o dari ese wa ji wa bi a ba ronupiwada, ko si ese ti o tobi ju fun un lati dariji niwon ti a ba wa ni irele otito pelu ironupiwada to ye, yi o dari ji wa. Eleda nfe ki a se atunse to dara lehin ironupiwada, o fe ki a yera patapata fun awon iwa ese ti atijo, o fe ki a rin lona to ye fun ijoba orun re. Bibeli wipe ‘Nitorina bi enikeni ba wa ninu Kristi, o di eda titun, ohun atijo ti koja lo, kiyesii o si di titun. (Kronika keji 5:17)
ADURA
Jesu Kristi olufe, o ti se ohun to ye fun igbala aye mi, o fi aye re rubo, o si ku ni Kalfari fun ese mi. mo ronupiwada ese mi looni, mo jowo won, mo si kowon sile. Mo gba Jesu Kristi ni Oluwa ati olugbala mi lati oni lo, mo pinu lati bere sise ise otun pelu re, mo si ko awon igbe aye atehinwa sile. Mo fi gbogbo iyoku aye mi sile fun o lati lo. Amin.
