OLORUN WA KO SE N BA FIGAGBAGA
Woli Elija fi han ijolooto re si Olorun han, o si doju ti awon Alagabagege. Woli yi penija awon olori ogun, bi oun ko tile ni iriri ogun jija. O rojo ina sori awon jagun jagun Ahabu, ti won gbiyanju lati muu. A koo wipe nigba naa ni oba ran olori ogun, aadota kan pelu aadota re o si goke too lo. Si kiyesii, o jokoo lori oke kan. Oun si wi fun un pe, iwo eniyan Olorun, oba wi pe sokale. Elijah si dahun, o si wi fun olori ogun aadota naa pe, bi emi ba nse eniyan Olorun, je ki ina ki o sokale lati orun wa, ki o run o ati aadota re. Ina si sokale ti Orun wa, o si run-un ati aadota re. Oun si tun ran olori ogun miran ati aadota re. On si dahun o si wi fun pe iwo eniyan Olorun, bayi ni oba wi, yara sokale, Elijah si dahun o si wi fun won pe, bi emi ba se eniyan Olorun, je ki ina ki o sokale lati orun wa, ki o si run o ati aadota re. Ina Olorun si sokale lati orun wa, o si run-un ati aadota re. (2 Awon Oba 1:9-12)
EKO
Olorun tobi, Olorun ni agbara, Olorun ni okun, ko si eni ti o le mu Olorun, ko si eni to le dinku agbara Olorun. Olorun kun fun ore-ofe, o si fe wa, sugbon ibinu re buru. O le fi ina run gbogbo aye, ki won si di eeru laarin iseju kan. Bi Olorun ba le gbe ese ibinu, gbogbo aye yi o daru, opolopo ni yio fara pa, ti won si jiya. Nitori naa gbogbo eniyan nilati beru Olorun, ki a si bowo to to fun-un. Oye ki a dupe lowo Olorun ti o lo agbara nla re fun anfani awa iran omo eniyan. Ko si eni to to lati gba iyinlogo ju Olorun awon Olorun ati Oba awon Oba, ti o ngbe ni orun, ti o si njoba ni aye. Niwon igba ti o je wipe a ko le foju ri Olorun, o ye ki a bowo fun iranse re ti a nfi oju ri. Awon asoju Olorun ni a fun ni agbara lati lo ase nipo re. Enikeni ti o ba ti bowo fun iranse Olorun, nbowo fun Olorun. Bakannaa, eni ti ko ba bowo fun iranse Olorun ko bowo fun Olorun. Lai si iyemeji, enikeni ti o ba nbu Olorun yi o jiya lati odo Olorun.
ADURA
Oluwa jowo ko mi ni eko lati bowo fun o ati lati bowo fun awon iranse re. Mase je ki nri o fin. Mase je ki nri awon iranse re fin ki iwo ma baa fi Iya jemi. Je ki n bowo fun awon iranse re ki nle di eni ibunkun. Jowo jeki nma beru re ki nsi pa ofun re mo ki emi baa le se rere ni orile alaaye. Ni oruke Jesu Kristi ni mo gba adura. Amin.
