E MA SE JE OLUGBO NIKAN
O ye ki awa Kristeni ki a ka, ki a si teti gbo oro Olorun, ki a si mu won lo, ninu isesi igbe aye wa. Won ro wa lati lo eko oro Olorun ati itoni inu bibeli fun anfani igbe aye wa. Bibeli wipe ‘Nitori bi enikan baje Olugbo oro naa, ti ko si je oluse oun dabi okunrin kan, ti o nsakiyesi oju ara re ninu awojiji. Nitori o sakiyesi ara re, o si ba tire lo, loju kan naa o si gbagbe bi oun ti ri. Sugbon eni ti o ba wo inu ofin pipe, ofun ominira nni, ti o si duro ninu re, ti oun ko je olugbo ti ngbagbe, bi ko se oluse-ise, Oluware yio je alabukun ninu ise re. (Jakobu 1:23-25).
EKO
Enikeni to baa nka ti o si nteti si oro Olorun lai fi sinu ise bi o ti ngbe igbe aye re ni ojojumo, Oluwa re je omode Kristeni. Olorun nfe ki Kristeni kookan maa dagba, ki a si di atojubo Kristeni. Agbalagba Kristeni kii se nipa ojo ori. A lee di agba Kristeni nipa biba Olorun ni ibadapo pelu Olorun Kristeni ti o ba fe dagba nilati maa gbadura, ki o si maa keko ninu oro Olorun. Bakanaa, agba Kristeni ni lati ja fafa ninu ise wiwaasu ihinrere. Awon agbalagba Kristeni nilati goke sii ise ijere okan, ati lati sin Olorun. Ohunkohun ti yio na won, won ko gbudo se pasiparo eri igbala won pelu ohun aye kan. Ki o ye wa wipe, Olorun ko lee gbe ise nla Pataki le omode Kristeni lowo. Oun yio se ise iyanu ati ohun nla nipase Kristeni ti o see nfi okan tan ti o si ti dagba ninu emi.
ADURA
Olorun Olufe jowo mu mi dagba, ki emi si di agbalagba Kristeni. Je kin je Kristeni ti o duro daradara. Je ki idapo mi pelu re ki o se deede, ki emi si maa te o lorun ninu gbogbo sise mi. Fun mi ni igboya lati le waasu ihinrere re, ki emi si je asoju re daradara ni ile aye yi. Je ki emi sin o daradara, ki emi ba ye fun gbigba ade ogo aidibaje ni orun. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
