OLORUN FERAN AWON ONIRELE
A nro Kristeni lati tele igbese Jesu Kristi, gege bi a ti koo wipe, Eni ero yii ninu yin, eyi ti o ti wa pelu ninu Kristi Jesu. Eni ti tile je aworan Olorun, ti ko kaa si iwora lati ba Olorun dogba. Sugbon O bo ogo Re sile, O si mu awo iranse, a si see ni awonran eniyan. Nigbati a si ti rii ni iri eniya, o re ara re sile, titi di oju iku, ani iku ori igi agbelebuu. Nitori naa Olorun pelu si ti gbee ga gidigidi, o si ti fi oruko kan fun un ti o bori gbogbo oruko, pe ni oruko Jesu ni ki gbogbo eekun ki o maa kunle, awon eni tin be ni orun, ati awon eni tin be ni ile ati awon tin be nisale ile. Ati pe ki gbogbo ahon ki o maa jewo pe, Jesu Kristi ni Oluwa, fun ogo Olorun baba (Filippi 2:5-11)
EKO
Iwa irele nwa saaju igbega, gbogbo Kristeni ni lati ri keeko iwa irele lati ara Jesu Kristi. Jesu Kristi ti o wa ni ipo keji ninu meta lokan, O ni ohun gbogbo fun ilo re ni Orun, o fi gbogbo owo nla re sile, O gba ki Olorun ree sile, ki o wa si aye lati wa gba araye la. Ni o ti jewo rire ara eni sile, Olorun wa fun ni ere pelu owo ti o dara ju. Gbogbo eniyan nilati jewo re ni Oluwa ki won to le ri igbala. Niwon ti Jesu ti re ara re sile, Olorun paa lase ki gbogbo5 eniyan jewo re gege bi Oga, gbogbo okan jewo re pe omo Olorun, ki a to le, gba ebun iye ayeraye. Bibeli so pato nipa Jesu wipe Nitori naa Olorun pelu si ti gbee ga gidigidi, o si ti fi oruko kan fun-un ti o bori gbogbo oruko, pe ni oruko Jesu ni ki gbogbo eekun ki o maa kunle, awon eni tin be ni orun ati awon eni ti nbe ni ile ati awon tin be nisale ile, ati pe ki gbogbo ahon ki o maa jewo pe, Jesu Kristi ni Oluwa, fun ogo Olorun Baba (Filippi 2:9-11)
ADURA
Olorun Olufe, jowo se mi ni onirele eniyan, funmi ni ore-ofe, irele bi omo re. Jesu Kristi, ti o re ara re sile fun itiju ati egan, nitori igbala omo eniyan. Ran mi lowo lati le re ara mi sile fun O, je ki emi maa ro nipa re, ki nsi maa sin O bo ti to. Lati se eleri ijewo mi, mo wole lese mi, mo jewo ese mi, mo gba Jesu Kristi ni Oluwa mi. Mo jewo pe Jesu ni Oluwa mi, mo si gbaa ni Olugbala mi. Lati akoko yi lo, emi yio sin Jesu Kristi pelu agbara mi, emi o si se eyi fun gbogbo ojo aye mi. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
