GBIYANJU LATI POLONGO IHINRERE NI GBOGBO ONA
Igboya ati Agbara ireti onigbagbo ni lati gbe igbe aye ti njeri didara Olorun. Ireti Kristeni ni lati je iru eyi ti Onisamu so wipe emi o wa ni agbara Oluwa Olorun, emi o maa da oro ododo re so, ani tire nikan. Olorun iwo ti ko mi lati igba ewe mi wa ati di isinsinyi ni emi ti nsoro ise iyanu re. Pelupelu, nigba ti emi di arugbo tan ti mo hewu, Olorun ma se ko mi titi emi o fi fi ipa re han fun iran yii, ati agbara re fun gbogbo awon iranti nbo leyin. (Orin Dafidi 71:16-18)
EKO
Ise Pataki ti Olorun fun onigbagbo kookan ni lati polongo inhinrere Jesu Kristi. Kristeni ni lati tan ina ihinrere. Olorun nipa ona awon alaigbagbo yio yi okan pada, won o si di eni igbala. Kikede,wiwaasu ihinrere je ise ti o rorun lati se. Gbogbo eniyan lo ye ki o maa so iriri igbala re pelu elomiran. (Boya ebi tabi ara ita) kio gba won niyanju lati ni ipin ninu ibukun kan na.
ADURA
Olorun Olufe, emi ko le se idupe tan, fun gbogbo oore, didara re ninu aye mi. Mo mo wipe, ikan lara fifi imore re han ni lati maa waasu ihinrere. Nitori naa fun mi ni ore-ofe lati maa rohin ihinrere, ki awon opo eniyan le di eni igbala. Jowo kun enu mi pelu Emi Mimo, ki o si lo mi gege bi ohun elo alaaye ti o ye fun mimu eso wa sinu ijoba re. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
