O NILO EMI IRELE LATI LE SE IFE OLORUN
Awon farisi fe da rudurudu sile laarin Johanu onitebomi ati Jesu Kristi, won si too Johanu wa pelu ibeere rikisi. Awon farisi wipe Rabbi, eni (Jesu) ti o ti wa pelu re, loke odo Jordani, ti iwo ti jeri re, woo, oun ni baptisii, gbogbo eniyan si nto o wa. (Johanu 3:26). Johanu ti o je iranse olorun so fun awon farisi wipe, oun ko to eni ti a le maa fi kegbe pelu Jesu, nitori Jesu je oga re Johanu so nipa ti Jesu eniyan ko le ri nkankan gba bi ko se pe a ba ti fi fun un lati orun wa. Eyin funra yin jerii mi pe, mo wipe, emi kii se Kristi naa, sugbon a ran mi siwaju re (Johanu 3:27-28). Johanu tun so fun awon farisi pe, oun ko le saima po sii, sugbon emi ko le saima dinku. Eni ti o ti oke wa ju gbogbo eniyan lo, eni ti o ti aye wa ti aye ni, a si maa so ohun ti aye, eni ti o ti orun wa ju gbogbo enyan lo
(Johanu 3:30-31).
EKO
Irele dara ju igberaga lo. Irele maa nmu ibola fun wa, sugbon igberaga maa nmu itiju wa. A ro gbogbo omo olorun ki a ni iwa irele. A ro wa ki gbogbo wa ni iwa irele okan bi ti Jesu Kristi, eni ti o ni gbogbo agbara ni ikawo, ti o wa re ara re sile titi de oju iku, ki o ba le gba elese to ti sonu la.
ADURA
Olorun olufe, jowo fun mi ni ore ofe ki nle wa ni ipo irele niwaju re nigba gbogbo. Ma se je ki ngberaga, ma si se je ki nru ara mi soke ju awon eniyan to ku. Ma se je kin ba o pin ninu ogo to je tire nikan, masi se je ki nbola re fun elomiran. Kun mi, ki o si fun mi ni agbara emi mimo lati maa se awon ohun ti o dara niwaju re ni gbogbo akoko. Bakan naa, je ki emi mimo re ran mi lowo lati maa ba awon eniyan se pelu ibowo fun, ki o le je ounfa lati maa yin oruko mimo re. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
