OLORUN NI FE IRONUPIWADA TO YE KORO
Dafidi se si olorun, o ri asise re, o si ronupiwada. O kigbe si olorun, o si wipe olorun saanu fun mi, gege bi iseun ife re , gege bi ironu opo aanu re nu irekoja mi nu kuro. We mi ni awemo kuro ninu aisedede mi, ki o si we mi nu kuro ninu ese mi. Nitori ti mo jewo irekoja mi, nigba gbogbo ni ese mi si nbe niwaju mi. Iwo, iwo nikan soso ni mo se si, ti mo se buburu yii niwaju re. Ki a le da o lare , nigba ti iwo ba nsoro, ki ara re ki o le mo, nigba ti iwo ba nse idajo. Kiyesii, ninu aisedede ni a gbe bi mi, ati ninu ese ni iya mi si loyun mi, kiyesii, iwo fe otito ni inu ati ni iha ikoko ni iwo o mu mi mo ogbon. Fi ewe hissopu fo mi, emi o si mo, we mi, emi o si fun ju egbon owu lo. Mu mi gbo ayo ati inu didun, ki awon egungun ti iwo ti run ki o le maa yo. Pa oju re mo kuro lara ese mi, ki iwo ki o si nu gbogbo aisedede mi nu kuro. Da aya titun sinu mi, olorun, ki o si tun okan diduro-sisin se sinu mi. Ma se sa mi ti kuro niwaju re ki o si se gba emi mimo re lowo mi. Mu ayo igbala re pada to mi wa, ki o si fi emi ominira re gbe mi duro.
(Orin Dafidi 51:1-12).
EKO
Olorun je alaanu, yi o si dariji ese ti a ba jewo ti a si ronupiwada won niwaju re. Olorun korira ese, yi o si yayo pelu enikeni ti o ba sa fun ese. Ededa ko ni ko elese ti o ba ronupiwada. Yi o dariji elese ti o ba ronupiwada, yi o si fun ni aye to ye ninu ijoba re. Bakan naa, elese ti o ba ko lati ronupiwada, yi o jiya ni orun ina apadi. Nitori na a ro gbogbo eniyan ki a yera fun dida ese, ki a le bo ninu ijoba Olorun ti o nbo lori gbogbo elese ti ko ronupiwada.
ADURA
Olorun olufe, mo gba pe elese ni mi, ti ko ye fun ibukun kankan lati odo re, mo ti da awon ese ti ko see fenu so, unko si ye fun orun rere. Mo ti ri awon asise mi, mo si to o wa pelu okan irele. Looni, mo ronupiwada ese mi, mo si beere ki o dariji mi. Jowo mu esan ese kuro ninu aye mi, gbami pada gege bi ikan lara ayanfe omo re, fun mi ni ore ofe ki emi mase pada sinu awon ese ti tele mo. Mu mi duro ninu igbagbo ti o dara, si se mi ni alaba pin ninu ibukun re ni aye yi ati ni orun. Nigbati opin ba de, ka mi mo awon ti yi o maa gbe pelu re ni orun titi ayeraye. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
