ONIGBAGBO GBODO TO OLORUN LO PELU ADURA
Oba Dafidi ba ara re ninu isoro, o si kigbe si olorun fun iranlowo. Oba yi ni igboya pe olorun yio dahun adura re, yoo si gba kuro ninu iponju re. Adura Dafidi bi a se koo niyi “Iwo o ti gbagbe mi pe to oluwa, laelae, iwo o ti pa oju re mo pe to kuro lara mi. Emi o maa gbimo ni okan mi pe to? Ti emi o maa ni ibinuje ni okan mi lojoojumo, ota mi yoo ti gberaga sori mi pe to? Roo, ki o si gbohun mi, Oluwa Olorun mi, mu oju mi mole, ki emi ki o ma baa sun orun iku. Ki ota mi ki o ma baa wipe, emi ti segun re, awon ti nyo mi lenu a si maa yo, nigbati a ba si mi nipo.
(Orin Dafidi 13:1-4).
EKO
Kristeni koni ohun ija ti o dara ju adura lo. A gba wa niyanju lati ke pe olorun ki a si te pepe ebe wa si iwaju re nigba gbogbo. Kosi idiwon ohun ti a le bere lowo olorun. O ni agbara lati yanju opolopo ebe wa ni akoko kan naa, yio si gbo ebe awon omo re. Pelu imo wipe awa kristeni kii se omo alailobii tabi alailagbara, o ye ki a rin tobaba wa ti nbe ni orun, ki a si beere ohunkohun ti a ba nfe. Idahun olorun si adura wa wonyi, sugbon ko pin si wonyi – aabo, ipese, igbega.
ADURA
Olorun olufe, mo loye pe iwo ni oba gbogbo aye, o ni ohun gbogbo ni ikawo, ko so ohun ti o soro fun o lati se, nitorina mo pe o si eto aye mi, mo beere fun iranlowo re, ba mi woo pale gbogbo oke ipenija ti o yi mi ka, wo won pale patapata, awon oke aisan, osi, ati gbogbo ofa/idojuko ota. Fun mi ni isegun ki o si pa mi lerin. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
