MAA SE YEPERE OORE-OFE OLORUN
Olorun doju ti Sennakeribu Oba Asiria, nitori pe o ri Olorun fin o si hale mo awon Israeli. Oba buburu gbogun ti Jerusalemu pelu awon omo ogun re, lati se idiwo ona ipese won, ki won si gba ilu won. O si ko leta si Oba Hesekiah ti Jerusalemu lati je ki agbara re dinku. Ninu leta re, Senakeribu, se afiwe ara Olorun alaye we awon orisa, o si wipe mase je ki Olorun re, eni ti iwo gbekele ki o tan o je wipe A ki yoo fi Jerusalemu le owo Oba Asiria. Kiyesii iwo ti gbo ohun ti awon Oba Asiria ti se si gbogbo ile, ni pipa won run patapata, a o ha si gba iwo bi? Orisa awon orile-ede ha gba awon ti awon baba mi ti parun, bi Gosani ati Harani, ati Resefu, ati awon Omo Edeni ti o wa ni Telassari? Nibo ni Oba Hamati, ati Oba Arpadi, ati Oba ilu Safarfaimu, ti Hena, ati Ifa gbe wa (2 Awon Oba 19:10-13).
Olorun da Oba Sannakeribu agberaga lohun, ti o pee nija. O si se ni oru naa ni Angeli Oluwa jade lo, o si pa oke mesan-an le egbeedogbon eniyan ni ibudo awon Asiria, nigba ti won si dide ni kutukutu owuro, kiyesii, oku ni gbogbo won jasi. Bee ni Sennakeribu Oba Asiria mu ona re pon, o si lo, o si pada, o si joko ni Ninefe. O si se bi o ti nborisa ni ile Nisroku orisa re ni Adrameleki ati Sareseri awon omo re fi ida paa, won si sa lo si ile Armeniyan, Esarhadoni omo re si joba ni ipo re (2 Awon Oba 19:35-37).
EKO
Ko si eda kan (eniyan) ti o lee ba Olorun jagun ki o si bori. Nigba ti oje Jehofa, yi o se ohun gbogbo lati se aabo oruko re. Nitori naa, gbogbo eniyan ye ki won beru re, ki won si bowo fun oruko mimo re. A ni lati bola fun, ki a mase fi we awon orisa. Gbogbo eniyan ye ki won mo wipe, aibowo fun Olorun le fa ibinu Olorun pelu ijiya nla.
ADURA
Olorun olufe, jowo fun mi ni ore ofe lati le maa b’owo fun O nigba gbogbo. Mase je ki emi mase alai bowo fun O. Je ki emi sin o pelu iyi ati owo. Je ki airi agbara re bukun mi, ki o si dara fun mi ni gbogbo aye mi. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
