AWON ONIGBAGBO TI GBA ISODOMO SINU EBI OLORUN
Awa Kristeni ni ajogun ijoba Olorun. Awa kii se eru, sugbon a je omo okunrin ati omo obinrin Oga Ogo ti a yan lati gbe ibi ti o dara ju ni aafin ijoba re. Awa ni ojulowo omo re bi bibeli ti wi, nje mo wipe, niwon igba ti arole naa ba wa ni ewe, ko yato ninu ohunkohun si eru bi o tile je Oluwa ohun gbogbo. Sugbon o wa labe olutoju ati iriju titi di akoko ti baba ti yan tele, gege bee si ni awa, nigba ti awa wa ni ewe, awa wa ni Onde labe ipilese eda. Sugbon nigba ti akoko kikun naa de, Olorun ran omo re jade wa, eni ti a bi ninu obinrin, ti a bi labe ofin. Lati ra awon tin be labe ofin pada, ki awa ki o le gba isodomo. Ati nitori ti eyin nse omo, Olorun si ti ran Emi omo re wa sinu oka yin, ti nke pe, Abba, Baba. Nitori naa, iwo kii se eru mo, bi ko se Omo, ati bi iwo ba I se omo, nje iwo di arole Olorun nipase Kristi (Galatia 4:1-7).
EKO
Olorun ti ran omo re Jesu Kristi ati Emi Mimo lati fi dani loju, isodomo Kristeni sinu ebi re, Kristeni wa ni idani loju pe a je omo Olorun nipa jijewo igbagbo ninu Jesu Kristi. Kristeni wa ni ipin ninu ibukun Olorun. Nipa lilo oruko Jesu Kristi, Kristeni le pase ohun gbogbo ki. O sise fun won. Ni pataki Onigbagbo ninu Jesu Kristi ni npongbe orun, won yoo si gba ade ogo aidibaje lehin opin ohun gbogbo.
ADURA
Olorun olufe, mo yin oruko re nipa siso mi di omo re, ninu ijewo igbagbo mi ninu Jesu Kristi. Mo yin o nipa mimu kuro ni eru ti o wa so mi di omo, lati igba ijewo Jesu Kristi, mo ti di omo Olorun, a si ti ko oruko mi sinu iwe iye. Eyin Olorun, orun ni ile mi, mo fi aye mi fun o looni, ni ola ati titi ayeraye. Ose Jesu Kristi fun ore ofe igbala re.
