L’OFE NI IHINRERE
Paulu ba awon ara Galatia wi, o wipe Eyin alaironu ara Galatia, ta ni ha tan yin je, ki eyin ki o ma se gba otito gbo, ni oju eni ti a fi Jesu Kristi han laari yin ni eni ti a kan mo agbalebuu (Galatia 3:1)
EKO
Gbogbo eniyan ni lati mo itumo Kristeni ki a si duro ninu re. Ihinrere Jesu Kristi je ofe, gbogbo eniyan ni lati gbaa ki o le ni igbala. Awon ara Galatia ko le gbaa, nitori o je asa won pe, aseyori ti enikeni ba ni, o je nipa ipa eniyan. Paulu ba awon Galatia wi, o fi han won ohun ti Kristeni je, ki won si duro ninu re. Paulu salaye wipe Nitori pe omo Olorun ni gbogbo yin, nipa igbagbo ninu Kristi Jesu. Nitori pe iye eyin ti a ti baptisi sinu Kristi, ti gbe Kristi wo. Ko le si Juu tabi Hellene, eru tabi ominira, okunrin tabi obinrin, nitori pe okan ni gbogbo yin je ninu Kristi Jesu. Bi eyin ba si je ti Kristi, nje eyin ni iru-omo Abrahamu, ati arole gege bi ileri. (Galatia 3:26-29)
ADURA
Olorun olufe, je ki o ye mi pe a nri igbala gba nipa ore-ofe ati igbagbo ninu Jesu Kristi. Je kin lo iyoku aye mi lati maa yo ayo igbala ofe ti mo ti ri gba. Jowo pami mo ninu ayo igbala re, emi yi o sin o ni gbogbo iyoku aye mi. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
