ADARI GBODO B’OWO FUN OLORUN
Bibeli toka si igbe aye aiwa bi Olorun awon adari Israeli si ti Oba Jeroboamu. Tani Jeroboamu? O je Oba Israeli ti o buru, o huwa ti ko dara, o mu ki Israeli ya kuro ni sisin Olorun ni otito. Jereboamu tako Olorun, o si se agbateru orisirisi orisa. O si se orisirisi ona sisin orisa (ninu awon orisa bibo yi, awon eniyan yio fi omo won se irubo) Olorun fiya je Jeroboamu fun gbogbo iwa buburu re. Gbogbo Oba to buru, ti o je lehin re ni a fi ntoka si iwa buburu Jeroboamu. Titi di oni yi, a sin ka ninu bibeli iwa buburu Oba Jeroboamu. Titi di oni yi, a sin ka ninu bibeli iwa buburu Oba Jeroboamu. Fun apeere, awon Oba lehin Joroboamu ni a salaye ni isale yi.
1. OBA SAKARIAH
Ni odun kejidinlogoji Asariah Oba Juda ni Sakariah Omo Jeroboamu joba lori Israeli ni Samaria ni osu mefa. O si se eyi ti o buru ni oju Oluwa, bi awon baba re ti se oun ko kuro ninu ese Jeroboamu omo Nebati, eni ti o mu Israeli se. (2 Awon Oba 15:8-9)
2. OBA MENAHEMU
Ni Odun Kokandinlogoji Asariah Oba Juda ni Menahemu Omo Gadi bere si joba lori Israeli, o si joba odun mewa ni Samaria. O si se eyi ti o buru ni oju Oluwa, Oun ko si lo kuro ninu ese Jeroboamu omo Nebati eni to mu Israeli se ni ojo re gbogbo.
3. OBA PEKAHIAH
Ni aadota odun Asariah Oba Juda, Pekahiah omo Menahemu bere si joba lori Israeli ni Samaria, o si joba odun meji. O si se eyi ti o buru ni oju Oluwa, oun ko si lo kuro ninu ese Jeroboamu omo Nebati eni ti o mu Israeli se (2 Awon Oba 15:23-24)
4. OBA PEKA
Ni Odun Kejilelaaadota Asariah Oba Juda ni peka Omo Remaliah bere si joba lori Israeli ni Samaria, o si joba ni Ogun odun. O si se eyi ti o buru ni oju Oluwa, oun ko lo kuro ninu ese Jeroboamu omo Nebati, eni ti o mu Israeli se. (2 Awon Oba 15:27-28)
EKO
Gbogbo adari (ipokipo ti won le wa) ni lati sora ki won mase si ipo won lo. Oko ni lati je apere to dara, iyawo ni lati je eni ti o ni iberu Oluwa, awon omo ni lati je apere to dara si ara won. Bakanaa, awon adari ni ipokipo (kapite, adari apapo eni ti a nto lehin, Oluso Aguntan, Senator, Gomina, Olori Orile Ede tabi ipo miran) ni lati lo ipo re daradara. Oni lati lo ipo re pelu iberu Olorun. A mo wipe ori ko le rin ki o ma ji, a lee se gba gbogbo asise wa. A nilati ronupiwada kuro ninu ese, ti a ba se asise kan, ki a se atunse to to. Olorun nfe ki a ni emi irele, ki a si gba asise wa. A ni lati se atunse nigba ti a ba ri aise deede wa, ki a si se amuye to ba to. Omo Olorun ni lati ni emi ti o ngba ikoni, ki o si gba atunse lori asise re. Olorun yio bukun awon eniyan ti ko kuna lati fun ibawi fun omo ti o ya ipanle tabi ipata (olokan to le). Yi o fiya je alaigboran omo, ti o ba ko lati yipada. Bakanaa, itan fi ye wa wipe, elese ko ni lo lai jiya, o ye ki o maa dun ni okan wa.
ADURA
Olorun olufe, je ki emi ko ihato dara si atunse. Fun mi ni emi irele, okan ti a lee ko. Je kin je olotito, ki emi si gba asise mi. Ran mi lowo lati gbe igbese itesiwaju, ki emi je Kristeni ti o ndagba, ti o faye gba iwa mimo, otito idurosinsin ati awon iwa to dara. Jowo se eyi ati awon ohun miran fun mi. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin
