IPO IWA MIMO NINU IGBEYAWO
Olorun seto igbeyawo ati mimo igbeyawo, O ni ki awon omo re gbeyawo, dipo ki won maa subu sinu idanwo ibalopo. Bibeli wipe nje ti awon ohun ti e ti kowe, o dara fun okunrin ki o maa fi owo kan obinrin. Sugbon nitori agbere, ki olukuluku ki o ni aya tire, ki olukuluku ki o si ni oko tire. Ki oko ki o maa se ohun ti o ye si aya, bee si ni aya pelu si oko (1 Korinti 7:1-3).
EKO
Awon omo Olorun ni a fi Bibeli se itoni won bi won se lee te Olorun lorun, ati bi won se le yera fun ese ibalopo Eleda gba awon omo re niyanju lati gbeyawo, ki won si fara mo iyawo won. (Olorun seto igbeyawo larin okunrin ati obinrin) bi eniyan ba ti se igbeyawo, yio fara mo bi yio ti se te enikeji re lorun, ti yio si tesiwaju ninu ise olorun. A waro gbogbo omo Olorun lati se igbeyawo, dipo sise awon nkan won-on-ni ti o le mu eeri ba ara, okan ati emi, ti yio gba ijiya Olorun.
ADURA
Olorun Olufe mo pinu lati lo igbe aye mi lati maa sin o ninu iwa mimo, emi o sa gbogbo ipa ati agbara mi lati sa fun ese, nipati ese ibalopo ti o ndoti ara, okan ati emi. Jowo ran mi lowo lati pa ara mi mo ni mimo, nipa yiyera fun ese pansaga ati agbere. Je ki nwa ni mimo ni ibamu pelu bibeli. Je ki emi wa ni mimo, niwaju re, ki emi lee ri ibukun re gba ni aye yi ati ni orun. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
