ADURA JE IRINSE PATAKI FUN ONIGBAGBO
Jabesi mo wipe oun ngbe igbe aye ti o wa labe egun, o si gbe igbese ti o fi gba ara kuro. Bibeli wipe Jabesi si se olola ju awon arakunrin re lo, iya re si pe oruko re ni Jabesi wipe, nitori ti mo bii pelu ibanuje. Jabesi si ke pe Olorun Israeli wipe, iwo iba je bukun mi, nitooto, ki o si so agbegbe mi di nla, ki owo re ki o si wa pelu mi, ati ki iwo ki o ma si je ki emi ri ibi, ki emi ma si ri ibanuje, Olorun si mu ohun ti o toro se (1 Kronika 4:9-10)
EKO
Adura ni agbara lati paa run ise Satani ninu aye eniyan. O le ma na wa ni owo, sugbon o je ohun elo lati doju ko ayidayida aye. Adura dabi ida oloju meji ti yio ge ohunkohun ti o ba koja ni ona re. Ko ye ki o nira rara. Ti a ba le la enu wa lati jeun, lati mu, ati lati soro, koye ki o je inira fun wa lati gbadura. Nitorinaa, ko si Kristeni ti o gbodo foju fo Pataki adura, sugbon ki a loo gege bi ohun elo lati yanju awon ohun ti o kan wa. Olorun ngbo adura awon eniyan re, yio si dahun adura wa. O nse itoju, yio si fun wa ni iseun ife re.
ADURA
Olorun Olufe jowo fun mi ni agbara lati maa gbadura ni gbogbo igba. Je ki emi lo adura lati segun gbogbo ogun aye mi. Je kin lo adura lati soro si, ki nsi bori gbogbo igbenija igbagbo mi, Alafia mi ati itesiwaju mi. Jowo dahun gbogbo edun okan mi nigba ti mo ba kegbe pe o, ki o si dara fun mi ni gbogbo ojo aye mi gbogbo. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin
