ARA WA JE PEPE OLORUN
Bibeli salaye idi re ti Kristeni ko gbodo da ese ibalopo. O wipe E maa sa fun agbere, gbogbo ese ti eniyan nda owa lode ara sugbon eni ti o nse agbere nse si ara oun funra re. Tabi eyin ko mo pe ara yin ni tempili Emi Mimo, tin be ninu yin, ti eyin ti gba lowo Olorun? Eyin kii sii se ti ara yin. Nitori ati ra yin ni iye kan, nitori naa e yin Olorun logo ninu ara yin, ati ninu emi yin, tii se ti Olorun (1 Korinti 6:18-20)
EKO
Olorun nfe ki a bola fun pelu ara mimo, okan ati Emi. Bibeli tile wipe Eyin ko mo pe ara yin ni tempili Emi Mimo (1 Korinti 6;19) o wa han gbangba pe, Olorun ko ni inu didun si awon ti o ba ndese ibalopo, yala yio se idajo won. O wa se Pataki ki gbogbo omo Olorun gbe igbe aye iwa mimo. Ese ibalope je ewo niwaju Olorun, gbogbo omo Olorun ni lati kaa si AISAN ki won si sa fun, Jehofa yio b’ola fun awon ti o ba bola fun pelu ara ati okan, sugbon yio da elese lebi lo si koto ina orun apadi, ayafi ti o ba ronupiwada.
ADURA
Olorun Olufe mo mo pe ese ibalopo je eewo niwaju re, nitori naa, mo fe dawo re duro ninu aye mi. mo kabamo fun gbogbo ese ibalopo ti mo ti da sehin, mo ti pinu lati maa gbe igbe aye iwa mimo niwaju re. Emi ko ni gba ese ibalopo laye mo. Lati akoko yi lo, emi yio yera fun ohunkohun ti o le doti okan mi. Emi yio siwo gbogbo iwa aimo. Emi yio maa gbe igbe aye iwa mimo. Kun mi pelu agbara Emi Mimo, ki emi le maa se ohun to to ni gbogbo igba. Lehin ire ije mi laye je ki a fun mi ni egba owo ni orun fun diduro deede pelu re. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere Amin.
