IGBIYANJU DIE SI A MAA PE FUN IPEJO TO JOJU
Iran-Ebi Efraimu ni a salaye bi won se tele ara won, ko si eniti a pe akiyesi re bikose ebi Aseri. A si kowe re pe gbogbo wonyi ni awon omo Aseri, awon olori ile Baba won, asayan alagbara akoni eniyan, olori ninu awon ijoye, iye awon ti a ka ye fun ogun, ati fun ija ni idile won je egbaa metala okunrin (1 Kronika 7:40)
EKO
Ife Olorun si awon omo Jakobu, laisi ariyan jiyan, o tobi. Sugbon a pe akiyesi wa fun awon ebi kan ju awon miran. Awon ti a se akiyesi won ni awon ebi ti won gbe igbese lati mu inu Olorun dun. Olorun bukun won, o si mu ki ibukun won ki o tayo ju awon ti o ku. Awa omo Olorun ni lati sa gbogbo ipa wa lati mu ki inu Olorun dun si wa, ti a ba fe tayo ni giga wa.
ADURA
Olorun Olufe, a ti mu mi ranti pe gbigbiyanju sii mi, yio fa akiyesi re. Nitori naa, fun mi ni ore-ofe lati sin sii. Ran mi lowo lati mu inu re dun, nipa fifi kun ise sinsin o. Ki emi lee ri ibukun ti o tayo gba ni aye yi ati ni orun. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
