IFE AISETAN ONIGBABGO SI OLORUN
Olorun nfe ife aisetan lati odo awon omo re, o fe ki a sin laisi rikisi kan. Yi o bukun wa bi a ba sin ni daradara, ise isin wa ko ni lati duro lori ohun ti a o ri gba pada bi esan. Ise isin kristieni ni lati dabi iru eyi ti wolii Habakuku so ninu Bibeli ‘Bi igi opoto ki yoo tile tanna, ti eso ko si ninu ajara, ise igi-olofi yoo je asedanu awon oko ki yoo si mu ounje wa, a o ke agbo-eran kuro ninu agbo, awon eran ki yoo si si ni ibuso mo. Sugbon emi yoo ma yo ninu Oluwa, emi o ma yoo ninu Olorun igbala mi, Oluwa Olorun ni agbara mi, oun o si se ese mi bi ese agbonrin lori ibi giga mi ni yoo si mu mi rin
(Habakuku 3:17-19)
EKO
Kristieni ko yato si awon eniyan miran, a ni ana wa (didan ati kikoro wa) Jesu wa wa ri o we wa mo, o gba wa la. Bi a tile se alaini ohunkan tabi omiran eredi sin sin Olorun ko ni lati ni atamo kokan, awon nkankan le je okunfa wiwa sodo Olorun, awon okunfa wonyi ti wa di ohun ti ko lagbara mo. Koko sinsin Olorun wa nilati duro lori aisi awawi kan, kristieni ni lati maa sin Olorun nigba ojo tabi bi orun nran. A nilati sin Olorun ninu ewa, boya ayika wa tu wa lara tabi ko tu wa lara, awa omo Olorun ko gbudo kariso bi eni ti ofo nla se, ti yi o fi ba idapo wa pelu Olorun je. Omo Olorun ni lati mu iduro won pelu Olorun daradara, boya a ri ireti wa gba tabi a ko ri won gba, Baba wa tin be ni orun ni agbara lati pese fun aini wa, yi o ba aini wa pade yio te wa lorun bi a ba le ni ife ti o pe sii.
ADURA
Olorun olufe opin de fifi o tayo, mo pinu lati ni idapo to peye pelu re, emi ko ni sin o nitori anfani ti mo le ri gba, sugbon emi yi o sin o tokan tokan, emi yi o fi akoko ati agbara ko orin didun, un o si gbadura si oruko mimo re. Emi yi o sin o, pin ihinrere ati lati ti awon ti o pin ihinrere lehin, emi yi o je ki Emi-Mimo ki o ko mi si otito iwe mimo, ati pelu, mo yonda gbogbo okan mi fun o Jesu Kristi. Jije olooto mi ati nini ife to peye yi o wa fun o ati fun o nikan, ijewo mi wa loni, lola ati laelae. Ni oruko Jesu Kristi ni mo se ijewo mi. Amin.
