YIYE FUN ORUN
A se inunibini si Paulu lati odo awon alase nitori ipa ti o ko nipa mimu ki ihinrere tan kale ati fun ikora eni nijanu, awon adari oselu bi Gomina Festu ati Gomina Feliksi won ko ni se idajo lori idibaje. Paulu wa gba idalebi idajo arekereke, o wa di eni ti a da lebi idajo ti ko duro deede, Bibeli wipe ‘Sugbon Festu nfe gba ojuure lodo awon Juu, o si da Paulu lohun o wi pe iwo ha nfe goke lo Jerusalemu, ki a si se ejo nnkan wonyi nibe niwaju mi bi? Paulu si wi pe niwaju ite idajo Kesari ni mo duro nibi ti o ye ki a se ejo mi, emi ko se awon Juu, bi iwo pelu ti mo daju.
(Awon Aposteli 25:9-10)
EKO
Kristieni ngbe pelu awon eniyan miran ninu aye rudurudu yi, awon adari ijoba je jegudu jera awon ara ilu si njiya. Sugbon kristieni ko ni doju ko inilara titi aye, a o ni iriri otun ninu aye titun ati orun titun ti Olorun yi o da. (Ifihan 21:1-5) awon eniyan buburu ki yio ni ipin ninu aye titun ati orun titun ti Olorun yi o da, ibugbe won yi o je ni orun apadi. O wa se Pataki ki gbogbo eniyan, awon asejoba ati ara ilu ki won ni ajose po pelu Jesu Kristi, ki won gbaa bi Oluwa won, ki won baa kun oju osuwon lati le ni ipin ninu aye titun ati orun titun tinbo.
ADURA
Olorun olufe lotito mo mo pe aye yi kun fun idibaje, ati pe aye titun ati orun titun unbo wa, mo fe nipin ninu re. Nitorina mo ronupiwada ese mi, mo si gba omo re Jesu Kristi ni Oluwa mi, jowo ka mi ye fun ijoba re, si ran mi lowo lati peye nipase iranlowo Emi-Mimo. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
